Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 3 (September 2016 sí February 2017)

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 3 (September 2016 sí February 2017)

Wo ibi tí iṣẹ́ dé lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láàárín September 2016 sí February 2017.

September 13, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Wọ́n ń fi katakata kó yẹ̀pẹ̀ sínú ọkọ̀ akẹ́rù tí wọ́n fi ń já yẹ̀pẹ̀. Ṣe ni wọ́n wa yẹ̀pẹ̀ jáde, tí wọ́n sì kó o lọ sáwọn ibòmíì lórí ilẹ̀ náà kí ilẹ̀ náà lè ṣe é kọ́lé sí.

September 15, 2016​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Àwọn òṣìṣẹ́ Ẹ̀ka Iná Mọ̀nàmọ́ná ń to àwọn wáyà tó ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ pọ̀. Ọ́fíìsì àti yàrá ìjẹun ni wọ́n á máa fi ilé yìí ṣe ní àárín ìgbà tí wọ́n bá ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun tó wà ní tòsí ibẹ̀.

September 19, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Fọ́tò tá a yà látòkè yìí jẹ́ ká rí ọ̀nà àlọyípo tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àti ọ̀nà tó wọ ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Lápá òsì ọ̀nà àlọyípo náà, wọ́n ń ṣètò láti ṣe ọgbà kékeré kan àti omi adágún síbẹ̀, títí kan ibi tí àwọn tó ń gbé ládùúgbò náà àtàwọn àlejò lè ti najú.

November 3, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Wọ́n ń fọ́ àwọn kọnkéré tí wọ́n kó jọ lórí ilẹ̀ náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n á sì tún un lò láti fi ṣe ọ̀nà sínú ọgbà náà.

November 4, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ tó wà níwájú yìí ń ṣe àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa lò fúngbà díẹ̀ àtèyí tí wọ́n máa fi sílẹ̀ títí lọ. Wọ́n ń tẹ́ nǹkan funfun kan tó rí bíi kápẹ́ẹ̀tì sí ojú ọ̀nà náà, ó máa jẹ́ kó rára gba ọ̀dà sí. Lápá ọ̀tún lọ́wọ́ inú nínú fọ́tò yìí, wọ́n ń fi katakata kilẹ̀ kó tó di pé wọ́n máa tẹ́ nǹkan funfun yẹn sí i.

November 5, 2016​—Ibi tí wọ́n ti ń gba ìsọfunni nípa ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun táà ń kọ́

Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ń wá gba ìsọfúnni ní ọ̀kan lára ibi méjìdínlógún (18) tí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé ṣètò káàkiri orílẹ̀-èdè Britain àti Ireland. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ló wá síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó sì wá ló yọ̀ǹda ara wọn láti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ náà.

November 28, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn tó ń bójú tó àyíká ń tọ́jú igi wílò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìn yìí kó má bàa kú. Ọ̀kan lára ọgọ́rùn-ún méje (700) igi tí wọ́n gbìn sí àgbègbè náà nìyí. Ìdí tí wọ́n ṣe ṣètò omi adágún tó wà níbẹ̀ yẹn ni pé kí omi lè máa ṣàn wá síbẹ̀ lọ́jọ́ tí òjò bá rọ̀ gan-an. Èyí á tún jẹ́ kí wọ́n lè tọ́jú omi òjò, kí wọ́n sì lò ó nígbàkugbà tí wọ́n bá fẹ́.

December 5, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Kùrukùru gba ojú ọjọ́ lọ́jọ́ yìí. Wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ bí wọ́n ṣe ń fi katakata kó yẹ̀pẹ̀ torí ilẹ̀ náà ti sún mọ́ àtiṣeé lò fún iṣẹ́ ìkọ́lé. Apàpọ̀ gbogbo yẹ̀pẹ̀ tí àwọn agbaṣẹ́ṣe kó lórí ilẹ̀ náà lè kún ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) irú àwọn ọkọ̀ akẹ́rù yìí, kó tún ṣẹ́ kù!

December 6, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn tó ń bójú tó àyíká ń fọwọ́ túlẹ̀ kí wọ́n tó gbin igi yí ká ọgbà tí wọ́n gbin oríṣiríṣi nǹkan sí yìí. Oríṣi igi mọ́kànlá (11) àti oríṣi ewéko mẹ́rìndínlógún (16) tó máa ń hù lágbègbè yìí ni wọ́n gbìn sínú ọgbà náà àti àyíká rẹ̀.

December 19, 2016​—Ilé Gbígbé

Ẹ̀rọ tó wà lápá òsì yẹn ń gbẹ́ ihò tí wọ́n máa fi pilẹ̀ ilé náà. Ọ̀tọ̀ ni ẹ̀rọ tí wọ́n máa kọ́kọ́ fi gbẹ́lẹ̀ náà. Wọ́n á wá máa rọ kọnkéré sínú ihò náà bí wọ́n ṣe ń yọ ẹ̀rọ tibí. Tí wọ́n bá ṣe é tán, wọ́n máa wá ṣe ohun tí àwọn agbaṣẹ́ṣe ń ṣe láàárín fọ́tò yìí láti parí ẹ̀. Wọ́n á gbé irin sínú kọnkéré náà. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta (360) irú ẹ̀ tí wọ́n ti ṣe láti pilẹ̀ àwọn ilé gbígbé.

December 29, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì síe

Láàárọ̀ ọjọ́ tí òtútù mú yìí, púlọ́ńbà kan ń de páìpù omi tó máa gbé omi wọ àwọn ọ́fíìsì tí wọ́n máa lò fúngbà díẹ̀.

January 16, 2017​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Wọ́n ń fi katakata kó ìdọ̀tí kúrò nínú omi adágún yìí tó wà nínú ọgbà náà. Ọ̀pọ̀ irú àwọn omi adágún yìí ni ìdọ̀tí kún inú ẹ̀, ó sì nílò àtúnṣe. Àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe eteetí àwọn omi náà ò ní jẹ́ kí yẹ̀pẹ̀ ya wọ ibẹ̀ tójò bá ń rọ̀, omi náà ò sì ní kún inú ẹ̀ ju bó ṣe yẹ. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) ẹja tí wọ́n rọra kó lọ sínú omi míì nínú ọgbà náà kí wọ́n tó máa bójú tó àwọn omi adágún tó nílò àtúnṣe.

January 17, 2017​—Ilé Gbígbé

Wọ́n ya fótò yìí látòkè láti apá ìlà oòrùn. Lọ́wọ́ iwájú, iṣẹ́ ń lọ lórí ìpìlẹ̀ méjì nínú àwọn ilé gbígbé náà. Nísálẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún, wọn ò tíì dé àwọn ihò tí wọ́n rọ kọnkéré sí yẹn. Nísàlẹ̀ lọ́wọ́ òsì, wọ́n ti da kọnkéré sórí wọn láti fi dé e. Lọ́wọ́ àárín, ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ́lẹ̀ yẹn ṣì ń gbẹ́lẹ̀ lọ.

January 23, 2017​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Òṣìṣẹ́ kan ń parí iṣẹ́ lórí férémù ilẹ̀kùn kan ní Ibi Ìgbàlejò kó tó di pé wọ́n kùn ún. Níbí yìí, àwọn àlejò máa lè rí ìpàtẹ kan tó ń ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé náà, wọ́n á sì lè rí bíṣẹ́ náà ṣe ń lọ láti ibì kan tó ga sókè.

February 14, 2017​—Ilé Gbígbé

Wọ́n fẹ́ de irin méjèèjì pọ̀. Irin pupa yìí ló máa ń jẹ́ kí ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbé ẹrù ròkè yí síbí sọ́hùn-ún. Ẹ̀rọ náà ga tó ilé alájà mẹ́tàlá, ó sì lè gbé ẹrù tó wúwo tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún (320) àpò sìmẹ́ǹtì.

February 15, 2017​—Ilé Gbígbé

Àwọn ihò tí wọ́n rọ kọnkéré sí láti fi pilẹ̀ ilé nìyí. Wọ́n ń fi ayùn rẹ́ kọnkéré náà kó má bàa ga ju bí wọ́n ṣe fẹ́ lọ. Wọ́n ṣì máa bo àwọn irin tó yọ láàárín ìkọ̀ọ̀kan wọn tí wọ́n bá ti dé e.

February 17, 2017​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn oníṣẹ́ iná fẹ́ ri ọ̀kan lára àwọn àmì JW.ORG mọ́ ara àwọn ògiri tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ibi àbáwọlé sí ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì náà.

February 17, 2017​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Bí títì àlọyípo tí wọ́n ṣe náà ṣe rí nìyí nígbà tí wọ́n parí ẹ̀. Mọ́tò máa ń pọ̀ lójú títì tó gba ibi àbáwọlé náà. Lọ́wọ́ òkè lápá òsì, ẹ máa rí àmì JW.ORG lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nìyẹn. Tí wọ́n bá ti parí iṣẹ́ lórí omi adágún àti ọgbà tó wà níbi àbáwọlé yìí, á jẹ́ kíbẹ̀ túbọ̀ rẹwà.

February 24, 2017​—Ilé Gbígbé

Níbi tí ọwọ́ ẹ̀rọ tó ń gbẹ̀rù ròkè yìí gùn dé, ìyẹn igba ó lé mẹ́tàlá (213) ẹsẹ̀ bàtà, ọwọ́ ẹ̀rọ náà gún dé ibi tí mẹ́rin nínú àwọn ilé gbígbé márùn-ún náà máa wà. Lọ́wọ́ iwájú, àwọn agbaṣẹ́ṣe ń da kọnkéré síbi tí wọ́n á máa gbé mọ́tò sí nísàlẹ̀ ọ̀kan lára àwọn ilé gbígbé náà. Wọ́n ti ri irin tí wọ́n máa fi mú kí àwọn òpó àtàwọn ògiri ilé náà lágbára dáadáa.