Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Philippines, Apá 2 (June 2015 sí June 2016)

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Philippines, Apá 2 (June 2015 sí June 2016)

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Philippines ti parí iṣẹ́ àtúnṣe ńlá tí wọ́n ń ṣe sí àwọn ilé ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn tó wà nílùú Quezon. Nínú àwọn fọ́tò yìí, ẹ máa rí bíṣẹ́ náà ṣe lọ àti bí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà láàárín June 2015 sí June 2016. Kò ju oṣù mélòó kan lọ táwọn ilé tí wọ́n tún ṣe náà fi ṣeé lò, wọ́n sì yà á sí mímọ́ ní February 2017.

lẹ́yìn tí wọ́n tún un ṣe tán. Àwọn ilé tí wọ́n kọ́ tàbí tí wọ́n tún ṣe nìyí:

  • Ilé 4 (Ilé Gbígbé)

  • Ilé 5 (Ẹ̀ka Tó Ń Gbohùn Sílẹ̀, Tó sì Ń Ṣe Fídíò, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn)

  • Ilé 6 (Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àyíká, Ẹ̀ka Tó Ń Tún Ọkọ̀ Ṣe, Ẹ̀ka Jórinmọ́rin)

  • Ilé 7 (Ẹ̀ka Kọ̀ǹpútà, Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé, Tó sì Ń Kọ́ Ọ, Ẹ̀ka Àtúnṣe Ilé, Ẹ̀ka Tó Ń Kó Ìwé Ránṣẹ́, Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè)

June 15, 2015​—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì

Àwọn tó ń da kọnkéré ń fi pákó ṣe ibi tí wọ́n máa rọ kọnkéré sí láti ṣe ọ̀nà téèyàn lè fẹsẹ̀ rìn tó máa so Ilé 1, 5 àti 7 pọ̀.

June 15, 2015​—Ilé 5

Kí àwọn káfíntà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, wọ́n kọ́kọ́ ń wo àwọn àwòrán tí Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ti àgbègbè Éṣíà/Pàsífíìkì ti ṣe sílẹ̀. Ní March 2016, wọ́n gbé ẹ̀ka náà kúrò ní Ọsirélíà lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Philippines.

June 23, 2015​—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì

Wọ́n ń fi katakata wú ọ̀nà kan tí ọ̀kọ̀ máa ń gbà tí wọ́n fi kọnkéré ṣe, kí wọ́n lè gbẹ́lẹ̀ síbẹ̀. Tí wọ́n bá gbẹ́lẹ̀ náà tán, àwọn páìpù omi tútù tó ń bá ẹ̀rọ amúlétutù ṣiṣẹ́ ni wọ́n máa gbé gbabẹ̀.

July 20, 2015​—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì

Tọkọtaya tó wa láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà yìí jọ ń ṣètò bí wọ́n á ṣe fi ẹ̀rọ jó irin tó máa wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tàwọn èèyàn á máa fẹsẹ̀ rìn gbà.

July 20, 2015​—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì

Àwọn òṣìṣẹ́ ń ri páìpù omi tútù gba àárín Ilé 4 àti 5.

September 18, 2015​—Ilé 5

Káfíntà kan ń fi ẹ̀rọ de ibi tó ṣeé gbé nǹkan lé mọ́ ojú wíńdò.

September 18, 2015​—Ilé 5

Òṣìṣẹ́ yìí ń tẹ́ kápẹ́ẹ̀tì. Torí àtidín ariwo kù, wọ́n tẹ́ kápẹ́ẹ̀tì sí gbogbo àjà kejì Ilé 5. Ẹ̀ka Tó Ń Gbohùn Sílẹ̀, Tó sì Ń Ṣe Fídíò ló ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àjà náà.

October 22, 2015​—Ilé 5

Àwọn tó ń kun ilé ń fi ọ̀dà tó ń ta ooru dà nù kun ìta ilé kan táwọn ọ́fíìsì wà. Ọ̀dà yìí máa ń ta ìtànṣán oòrùn dà nù, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí inú ilé tutù, ó tún ń dín owó tí wọ́n á máa ná sórí ẹ̀rọ tó ń múlé tutù kù.

February 10, 2016​—Ilé 4

Òṣìṣẹ́ kan ń yọ pákó tí wọ́n kàn láti fi gbé kọnkéré dúró sára ògiri kúrò. Ilé alájà méjì ni Ilé 4, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ Bíbélì lóríṣiríṣi máa ń lò.

February 10, 2016​—Ilé 4

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣètò ẹ̀rọ tó ń múlé gbóná, tó ń fẹ́ atẹ́gùn, tó sì ń múlé tutù ń wé nǹkan mọ́ àwọn páìpù omi tútù. Ohun tí wọ́n ń wé mọ́ àwọn páìpù náà máa jẹ́ kí ẹ̀rọ tó ń mú kómi tutù ṣiṣẹ́ dáadáa, omi ò sì ní máa rin lára àwọn páìpù náà.

February 16, 2016​—Ilé 4

Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan láti Ọsirélíà ń yẹ àwọn wáyà yìí wò bóyá wọ́n gbéná wọlé. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún kan (100) àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó wá láti orílẹ̀-èdè míì láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú ilé tí wọ́n ń tún ṣe náà.