Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Ń Tu Àwọn Arúgbó Nínú, Wọ́n sì Ń Fún Wọn Nírètí

Wọ́n Ń Tu Àwọn Arúgbó Nínú, Wọ́n sì Ń Fún Wọn Nírètí

Bíi ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn arúgbó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Ọsirélíà. Wọ́n máa ń gbé àwọn kan lọ sí ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú arúgbó, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ sì máa ń fìfẹ́ tọ́jú wọn lójoojúmọ́.

Òótọ́ kan ni pé kì í ṣe àbójútó ìlera nìkan ni ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó yìí máa ń nílò. Ìgbà míì wà tí nǹkan máa ń sú wọn, wọ́n máa ń dá wà, ó tiẹ̀ máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò ní olùrànlọ́wọ́. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ ṣèbẹ̀wò sí ilé méjì tí wọ́n ti ń tọ́jú arúgbó nílùú Portland, tó wà ní Victoria lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Wọ́n máa ń lọ tù wọ́n nínú, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí fún wọn.

Wọ́n Dìídì Ṣètò Ìjíròrò Tó Dá Lórí Bíbélì fún Àwọn Arúgbó

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú náà máa ń pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn arúgbó, wọ́n á sì jọ máa jíròrò ohun tó wà nínú Bíbélì, bí àpẹẹrẹ, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú ayé Jésù. Jason sọ pé, “A máa ń ka ìtàn yẹn látinú Bíbélì sí etí àwọn arúgbó, àá sì bá wọn jíròrò ohun tó wà nínú ìtàn náà.” Ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó tó máa ń wá síbi ìpàdé náà ló ń bá àìlera yí, torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa ń sọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí àti ìṣírí fún wọn. Wọ́n máa ń sọ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa mú àìsàn àti ikú kúrò.

Tony, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú yẹn sọ pé, “Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í pàdé pẹ̀lú àwọn arúgbó náà, ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú la fi bẹ̀rẹ̀, àmọ́ wọ́n ní ká fi kún un. Torí náà, nǹkan bíi wákàtí kan la fi máa ń jíròrò báyìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyá arúgbó kan sọ pé ká sọ ọ́ di wákàtí méjì!” Àwọn kan lára àwọn arúgbó yẹn ò ríran, àwọn kan ò lè dìde lórí ibùsùn, àwọn míì ò sì lè di nǹkan mú. Torí náà, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣèrànwọ́ fún wọn jálẹ̀ àkókò tí wọ́n fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń rọ̀ wọ́n pé káwọn náà dá sí i bí agbára wọn bá ṣe gbé e tó.

Ara ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe níbẹ̀ ni pé àwọn àtàwọn arúgbó náà jọ máa ń fi àkókò díẹ̀ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn arúgbó yẹn sì sábà máa ń sọ pé àwọn fẹ́ kọ sí i. Ọ̀kan nínú wọn tó ń jẹ́ John * sọ pé: “A fẹ́ràn orin tẹ́ ẹ̀ ń kọ. Ó máa ń jẹ́ ká mọ Ọlọ́run, ká sì bọ̀wọ̀ fún un.” Arúgbó kan tí kò ríran, tó ń jẹ́ Judith ti há gbogbo ọ̀rọ̀ àwọn orin tó fẹ́ràn jù sórí!

Ọ̀rọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arúgbó náà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lógún. Brian tó yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣèrànwọ́ sọ pé tí ara àwọn arúgbó náà ò bá yá, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń lọ kí wọn nínú yàrá wọn. Ó ní, “A máa ń bá wọn sọ̀rọ̀, àá sì wo bí ara wọn ṣe ṣe sí. Ìgbà míì wà tá a máa ń pa dà lọ wo ẹni tí ara rẹ̀ ò yá ká lè mọ̀ bóyá nǹkan ti ń yàtọ̀.”

“Ọlọ́run Ló Rán Yín sí Wa”

Ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó tó ń gbé níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú wọn ló mọyì bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe wá ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Peter, tó máa ń lọ síbi tí wọ́n ti ń jíròrò Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi kí n ti wà níbẹ̀.” Judith sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ tó ń tọ́jú ẹ̀ pé: “Òní ni Wednesday o! Ẹ jọ̀ọ́, ẹ múra fún mi kí n lè lọ síbi tá a ti máa jíròrò Bíbélì. Mi ò fẹ́ pẹ́ débẹ̀!”

Àwọn arúgbó yẹn ń gbádùn ohun tí wọ́n ń kọ́, wọ́n sì sọ pé àwọn ti sún mọ́ Ọlọ́run ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nígbà kan, lẹ́yìn tí wọ́n jíròrò ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ Jésù, Robert sọ pé: “Apá ibí yìí nínú Bíbélì ò yé mi rí. Ó ti wá yé mi báyìí!” David ti kọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká máa gbàdúrà, ó sì sọ pé: “Ó ti jẹ́ kí n sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì ti jẹ́ kí n rí Ọlọ́run bí ẹni gidi.”

Inú àwọn arúgbó náà máa ń dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Lynette sọ pé, “Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ̀ ń fi Bíbélì tù wá nínú.” Arúgbó míì sọ pé: “Ọlọ́run ló rán yín sí wa!”

Margaret máa ń gbádùn àsìkò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò pẹ̀lú wọn débi pé ó ti ń lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba báyìí. Kì í ṣe ohun tó rọrùn fún un rárá torí ìlera rẹ̀ ò dáa, kò sì lè fi bẹ́ẹ̀ lọ sókèsódò. Ó sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé: “Ẹ ti jẹ́ kí gbogbo wa nírètí, káyé wa sì nítumọ̀.”

‘Ohun Ìyanu Lẹ̀ Ń Ṣe’

Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé tí wọ́n ti ń tọ́jú arúgbó náà mọyì bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe máa ń wá síbẹ̀. Anna, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú náà sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ máa ń rọ àwọn arúgbó náà pé kí wọ́n wá síbi tá a ti máa ń jíròrò torí wọ́n kíyè sí i pé tá a bá jíròrò tán, inú àwọn arúgbó yẹn máa ń dùn gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Brian tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fi kún un pé: “Ara àwọn òṣìṣẹ́ yẹn yá mọ́ọ̀yàn, wọ́n sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa. Ohun tá ò retí pé kí wọ́n ṣe ni wọ́n máa ń ṣe láti ṣèrànwọ́.”

Inú àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn arúgbó yìí máa ń dùn tí wọ́n bá rí bí àwọn èèyàn wọn ṣe ń gbádùn àwọn ìjíròrò Bíbélì náà tó. Ọmọ ìyá arúgbó kan gbóríyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ní: “Ohun ìyanu gbáà lẹ̀ ń ṣe fún mọ́mì mi.”

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí orúkọ àwọn arúgbó tá a mẹ́nu bà níbí pa dà.