Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

WATCHTOWER LIBRARY

Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè—Watchtower Library

Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè—Watchtower Library

Kọ̀ǹpútà tó o bá fẹ́ fi Watchtower Library sórí ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ irú èyí tó ń lo ètò ìṣiṣẹ́ Pentium tàbí ohun tó ju ìyẹn lọ. Ó tún gbọ́dọ̀ máa lo Microsoft Windows 7 tàbí èyí tó ju ìyẹn lọ. Àyè RAM tó fẹ́ fi ètò ìṣiṣẹ́ náà sí lórí ẹ̀ kò gbọ́dọ̀ dín sí 48 MB. Àyè tó ṣófo lórí C: drive kọ̀ǹpútà náà kò sì gbọ́dọ̀ dín sí 3 GB.

Àkíyèsí: Tó bá jẹ́ pé Windows 7 ni kọ̀ǹpútà ẹ ń lò, àfi kó o kọ́kọ́ lọ wá ètò ìṣiṣẹ́ tá a jẹ́ kó o lè lo fáìlì ISO lórí kọ̀ǹpútà náà. Ó lè rí ètò ìṣiṣẹ́ yìí lórí ìkànnì Microsoft.

 

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé léraléra ló gbìyànjú láti gbé ohun tuntun sórí Watchtower Library rẹ, àmọ́ tí kò ṣe, jọ̀wọ́ ṣe àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè fi ohun tuntun sí i fúnra rẹ:

  1. Lọ sí abala Wa Watchtower Library Tó Dé Kẹ́yìn Jáde lórí ìkànnì jw.org.

  2. Wa Watchtower Library tó dé kẹ́yìn fún èdè rẹ jáde.

  3. Tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà ní ìsọ̀rí “Fi Fáìlì Tó Ní Ohun Tuntun Sórí Kọ̀ǹpútà Ẹ.”

Ti ìyẹn kò bá yanjú ìṣòro náà, ṣe àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí:

  1. Ṣí File Explorer, lẹ́yìn náà, lọ sí “C:\ProgramData\Watchtower\WTLibrary.”

  2. Yọ (delete) àwọn fáìlì méjì yìí kúrò:

    • a. ca-bundle.zip

    • b. cert.pem

Tó bá ṣòro fún ẹ láti ṣe àwọn ohun tó wà lókè yìí, o lè bi ọ̀rẹ́ rẹ tó mọ̀ nípa Watchtower Library pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó sún mọ́ ẹ.

 

O lè ní kí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó mọ Watchtower Library lò dáadáa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ìyẹn kó bá ṣeé ṣe, jọ̀ọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó sún mọ́ ẹ.