Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ibi tí Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-Èdè Sweden ti gbọ́ díẹ̀ lára ẹjọ́ náà

DECEMBER 18, 2019
SWEDEN

Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Sweden Sọ Pé Ẹ̀sìn Tó Ń Ran Aráàlú Lọ́wọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Sweden Sọ Pé Ẹ̀sìn Tó Ń Ran Aráàlú Lọ́wọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Láti January 1, ọdún 2000, ni ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden ti ń lo Òfin Tó Wà fún Ṣíṣe Ìtìlẹ́yìn fún Ẹ̀sìn láti máa fowó ìjọba ṣètìlẹ́yìn fun àwọn ẹlẹ́sìn. Àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n ń fi owó tì lẹ́yìn láwọn ẹ̀sìn tó ń “fi ìlànà táá jẹ́ káwọn èèyàn máa gbé ní ìrẹ́pọ̀ kọ́ni, tí kì í jẹ́ kí irú ìlànà bẹ́ẹ̀ pa rẹ́” àti ẹ̀sìn“tó ṣeé gbára lé tó sì ń nípa rere lórí àwọn èèyàn.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú ẹ̀sìn tó wà ní Sweden nìjọba ń fowó tì lẹ́yìn, láti ọdún 2007 ló ti kọ̀ láti máa fowó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé wọ́n kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìsapá, àwọn ará gbé ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden lọ sílé ẹjọ́ nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni Ilé Ẹjọ́ Gíga dẹ́bi fún ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden pé ohun tí wọ́n ṣe ò bófin mu bí wọ́n ṣe kọ̀ láti fi owó ìjọba ṣètìlẹ́yìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ yí ìpinnu náà pa dà.

Níkẹyìn, ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden yí ìpinnu wọn pa dà ní October 24, ọdún 2019, wọ́n sì gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “kúnjú ìwọ̀n gbogbo ohun tí òfin béèrè fún” láti rí owó ìtìlẹ́yìn ìjọba gbà.

Irú ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní orílẹ̀-èdè Norway, níbi tí ìjọba ti máa ń fún gbogbo ẹ̀sìn, tó fi mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní owó ìtìlẹ́yìn lóòrèkóòrè. Ṣùgbọ́n, ní àwọn oṣù mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n ní kí ìjọba tún yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa bóyá ó yẹ kí wọ́n máa fi owó ìjọba ṣètìlẹ́yìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Èyí wá mú kí àwọn ará wa fún àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Norway ní ìsọfúnni tó péye nípa ojú tá a fi ń wo ọ̀rọ̀ òṣèlú. Wọ́n tún fún ìjọba ní ẹ̀dà àwọn ìwé tó ṣàlàyé bí Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-Èdè Sweden ṣe dá wa láre àti bí àwọn ilé ẹjọ́ míì ṣe dá wa láre ní orílẹ̀-èdè Jámánì àti Ítálì.

Inú wa dùn pé ní November 18, ọdún 2019, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Norway sọ pé ìjọba gbódọ̀ máa fi owó ṣètìlẹyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí wọ́n fi parí ọ̀rọ̀ wọn ni pé: “Ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè Sweden ló jẹ́ láti dìbò nígbà ìdìbò, àmọ́ kì í ṣe tipátipá fẹ́ni tí kò bá wù. Ó jọ pé lára ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ ni pé kò yẹ káwọn máa dìbò, . . . [ṣùgbọ́n] kò wá yẹ kí [ìjọba] rí èyí bí . . . ìdí tó bófin mu láti má ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní owó tí ìjọba fi ń ṣètìlẹ́yìn.”

Nígbà tí Arákùnrin Dag-Erik Kristoffersen, láti ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Scandinavia, ń sọ̀rọ̀ lórí ìpinnu yìí, ó ní: “Inú wa dùn pé ìjọba ti wá rí i pé à ń ṣe ohun tó dáa fáwọn aráàlú. A nírètí pé àwọn orílẹ̀-èdè míì tí ìjọba ti ń fowó ṣètìlẹ́yìn fáwọn ẹlẹ́sìn á kíyè sí ẹjọ́ tílé ẹjọ́ dá yìí.” Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a fi ọpẹ́ fún Jèhófà, Afúnnilófin wa Gíga Jù Lọ.—Àìsáyà 33:22.