Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 25, 2022
FARANSÉ

A Mú Ìwé Mátíù Jáde Lédè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé

A Mú Ìwé Mátíù Jáde Lédè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé

Ní February 19, 2022, Arákùnrin Didier Koehler tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tí orílẹ̀-èdè Faransé mú Bíbélì Ìhìn Rere Nípasẹ̀ Mátíù jáde ní Èdè àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé (LSF). A lè wa ìwé náà jáde lórí Ìkànnì jw.org àti JW Library Sign Language. Èyí ni ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì Mímọ́ Ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa mú jáde ní èdè LSF.

A ṣe àtagbà ètò bá a ṣe mú Bíbélì náà jáde, àwọn tó tó ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) ló sì wo ètò náà. Nínú àsọyé tí Arákùnrin Koehler sọ, ó ṣàlàyé pé: “Torí pé ohun tó ṣeé fojú rí ni èdè LSF, ẹni tó ń sọ èdè adití náà ṣàlàyé ẹ̀ lọ́nà tó gbà yé àwọn èèyàn dáadáa. Ó fi ojú, ara àti ìrísí ẹ̀ gbé èrò àwọn tó wà nínú ìtàn Bíbélì náà jáde.”

Láti nǹkan bí ọdún 1968 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ní èdè LSF. Nígbà tó di nǹkan bí ọdún 1972, wọ́n dá ìjọ àkọ́kọ́ tó ń sọ èdè LSF sílẹ̀ ní agbègbè Parisian ní Vincennes, lórílẹ̀-èdè Faransé. Lọ́dún 2002, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Faransé ṣètò ọ́fíìsì fáwọn atúmọ̀ èdè LSF. Kí àrùn Kòrónà tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2019, a kó àwọn atúmọ̀ èdè náà lọ sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Louviers, lórílẹ̀-èdè Faransé. Ní báyìí, ìjọ mọ́kànlá (11) àti àwùjọ mọ́kàndínlógójì (39) ló ń sọ èdè adití ní agbègbè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Faransé ń bójú tó.

Ọ̀kan lára àwọn ìpàdé àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe ní ìjọ tó ń sọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé nílùú Vincennes, ní Ilẹ̀ Faransé ní nǹkan bí ọdún 1972. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjọ yìí máa ń jókòó yípo kí wọ́n lè rí ìdáhùn tí ẹnì kan bá ń fọwọ́ sọ.

Ìwé Ìhìn Rere Mátíù la kọ́kọ́ mú jáde ní èdè LSF, ìwé Ìhìn Rere Jòhánù lá sì máa mú jáde tẹ̀ lé e. Àwọn èèyàn mọ àwọn ìwé ìhìn rere méjèèjì yìí dáadáa, ọ̀nà tí wọ́n sì gbà kọ wọ́n jẹ́ kó rọrùn láti túmọ̀ ju àwọn ìwé Bíbélì tó kù lọ. Ká tó mú ìwé Mátíù yìí jáde, ìwọ̀nba ẹsẹ Bíbélì díè làwọn akéde ní lédè LSF.

Arábìnrin kan tó jẹ́ adití, tó sì wa lára àwọn atúmọ̀ èdè LSF sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní kékeré, àwòtúnwò ni mo máa ń wo àwọn àwòrán inú ìwé Okunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí mo ṣe ń wo ìwé Mátíù ní èdè LSF, ṣe ni mò ń rántí gbogbo àwọn àwòrán náà. Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi, mo lóye Bíbélì dáadáa.”

Ẹlòmíì tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Adití làwọn òbí mi, ó sì wù mí kí wọ́n ní Bíbélì lédè LSF. Àmọ́, mi ò ronú ẹ̀ láé pé màá wà lára àwọn atúmọ̀ èdè tó máa ṣiṣẹ́ lórí Bíbélì náà, ẹ̀bùn ńlá ni Jèhófà fún un mi.”

Àwọn atúmọ̀ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé ń ṣe fídíò ní yàrá ìgbohùnsílẹ̀ wọn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Louviers, nílẹ̀ Faransé

Bíbélì tá a mú jáde lédè LSF yìí mú inú wa dùn gan-an. Ó sì jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn wa “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”​—Ìfihàn 22:17.