Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 14, 2017
ÍŃDÍÀ

Òjò Alátẹ́gùn Tó Lágbára Gan-an Ba Ìlú Mumbai Jẹ́

Òjò Alátẹ́gùn Tó Lágbára Gan-an Ba Ìlú Mumbai Jẹ́

Òjò alátẹ́gùn tó lágbára gan-an rọ̀ ní Mumbai, lórílẹ̀-èdè Íńdíà, ní ọ̀sẹ̀ August 28, ó sì yọrí sí ikú àwọn èèyàn mẹ́rìnlá [14].

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Íńdíà ròyìn pé kò sí ẹni tó kú tàbí tó fara pa gan-an lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni omi ya wọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yẹn fún àwọn ará wọn tí ilé wọn bàjẹ́ ní oúnjẹ, wọ́n sì bá wọn palẹ̀ ìdọ̀tí ilé wọn tó bàjẹ́ mọ́.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Íńdíà ń kíyè sí bí nǹkan ṣe lọ sí ní Mumbai àti àwọn apá ibòmíì ní Íńdíà tí omíyalé náà dé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

India: Tobias Dias, +91-9845476425