Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ibi tí omíyalé ti ṣọṣẹ́ ní Guatemala (apá òsì) àti Costa Rica (apá ọ̀tún)

NOVEMBER 20, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ìjì Líle Eta Ṣọṣẹ́ ní Central America, Cayman Islands, Bahamas, Jàmáíkà, Mẹ́síkò àti Amẹ́ríkà

Ìjì Líle Eta Ṣọṣẹ́ ní Central America, Cayman Islands, Bahamas, Jàmáíkà, Mẹ́síkò àti Amẹ́ríkà

Ibi tó ti ṣẹlẹ̀

Central America, Bahamas, Grand Cayman Island, Jàmáíkà, Mẹ́síkò àti apá gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ohun tó ṣẹlẹ̀

  • Ìjì líle Eta jà nílùú Puerto Cabezas tó wà lórílẹ̀-èdè Nikarágúà, ní November 3, 2020. Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣọṣẹ́ láwọn apá ibòmíì ní Central America, ó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́

  • Ó dùn wá pé ọ̀gbàrá òjò gbé ọmọkùnrin kan lọ nílùú Tabasco lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lọmọ náà, ọmọ ọmọ tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sì ni

  • Nígbà tọ́wọ́ ìjì yẹn rọlẹ̀ díẹ̀, ó ṣọṣẹ́ ní Grand Cayman Island, Bahamas àti orílẹ̀-èdè Jàmáíkà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún ṣọṣẹ́ lápá ibi tí òkun ti ya wọ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àtàwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe kan àwọn ará wa

  • Costa Rica

    • Àwọn akéde méjìdínláàádọ́fà (108) ló fi ilé wọn sílẹ̀

    • Àwọn akéde méje pàdánù gbogbo nǹkan ìní wọn

  • Guatemala

    • Àwọn akéde mẹ́tàlélọ́gọ́jọ (163) ní láti fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn márùndínláàádọ́rùn-ún (85) ti pa dà sílé

    • Ìdílé mẹ́ta pàdánù gbogbo nǹkan ìní wọn

    • Bákan náà, àwọn akéde mẹ́ta tó wà nínú ìdílé kan há sí àjà kejì ilé wọn kó tó di pé wọ́n wá gbà wọ́n sílẹ̀

  • Honduras

    • Àwọn akéde ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (1,984) ní láti fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ó kéré tán àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (376) ti pa dà sílé

  • Jàmáíkà

    • Àwọn akéde mẹ́rin ní láti fi ilé wọn sílẹ̀

  • Mẹ́síkò

    • Ní ìpínlẹ̀ Chiapas àti Tabasco, àwọn akéde ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìdínlógún (1,618) ló fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn méjìléláàádọ́fà (112) ti pa dà sílé

  • Nikarágúà

    • Àwọn akéde ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìdínlógójì (238) ló ní láti fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìlélọ́gbọ̀n (232) ti pa dà sílé

  • Panama

    • Àwọn akéde mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ló fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn mẹ́fà ti pa dà sílé

  • Amẹ́ríkà

    • Àwọn akéde méjìdínláàádọ́ta (48) ló fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ti pa dà sílé

Àwọn nǹkan tó bà jẹ́

  • Bahamas

    • Ilé kan bà jẹ́

  • Costa Rica

    • Ilé mẹ́ta bà jẹ́ kọjá àtúnṣe

    • Ilé mẹ́fà bà jẹ́

  • Guatemala

    • Ilẹ̀ tó ya ba ilé méjì jẹ́ kọjá àtúnṣe

  • Honduras

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba méje bà jẹ́ díẹ̀

  • Nikarágúà

    • Ilé mẹ́tàléláàádọ́rin (73) bà jẹ́

  • Grand Cayman Island

    • Ilé mẹ́rin bà jẹ́

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́ díẹ̀

  • Jàmáíkà

    • Ilé tó tó àádọ́ta (50) bà jẹ́

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́

  • Amẹ́ríkà

    • Ilé tó tó mọ́kànlélógóje (141) bà jẹ́

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́sàn-án (9) bà jẹ́ díẹ̀

Bá a ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́

  • Ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America yan ìgbìmọ̀ mẹ́ta láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará wa, méjì lára wọn wà ní Mẹ́síkò, ọ̀kan tó kù sì wà ní Honduras. Láwọn orílẹ̀-èdè míì tí àjálù yìí ti ṣẹlẹ̀, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tá a yàn nítorí àrùn Corona ló ń bójú tó ohun táwọn ará nílò

  • Ìjọ àtàwọn Ìgbìmọ̀ tá a yàn nígbà àrùn Corona ń pèsè ohun táwọn ará nílò láwọn ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń bójú tó

  • Àwọn alábòójútó àyíká ń fún àwọn ará níṣìírí látinú Bíbélì, ní pàtàkì àwọn ìdílé tó wà níbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀

  • Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà níbi tí àjálù náà ò dé ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó sá kúrò nílé, wọ́n ń gbà wọ́n sílé, wọ́n sì ń fún wọn lóúnjẹ

  • Àwọn ará wa rí i pé àwọn ń tẹ̀ lé òfin táwọn elétò ààbò ṣe lórí àrùn Corona bí wọ́n ṣe ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà bá

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìjì líle yìí bà jẹ́, inú wa dún gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ará wa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Ó dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run wa á máa bá a lọ láti jẹ́ ‘ibi ààbò fún wa lákòókò wàhálà.’​—Sáàmù 9:9.