Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Ibì Kọ̀ọ̀kan

Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Ibì Kọ̀ọ̀kan

Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n ní March 2024

ORÍLẸ̀-ÈDÈ

IYE TÓ WÀ LẸ́WỌ̀N

ÌDÍ

Crimea

12

  • Wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run

Eritrea

36

  • Wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run

  • Wọn ò sọ ohun tó fà á

Rọ́ṣíà

117

  • Wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run

Singapore

11

  • Ẹ̀rí ọkàn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun

Àwọn Ilẹ̀ Míì

Ó lé ní 21

  • Wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run

Àròpọ̀

Ó lé ní 197

 

Àpilẹ̀kọ kejìdínlógún (18) nínú àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights sọ pé ara ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni “ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá gbà láyè àti ẹ̀sìn tó wuni.” a Àmọ́ láwọn ilẹ̀ kan, wọ́n ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí, wọ́n tiẹ̀ máa ń hùwà ìkà sí wọn. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n fi ẹ̀tọ́ wọn dù yìí ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Wọ́n fi àwọn míì sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun.

a Tún wo ìwé United Nations Universal Declaration of Human Rights, Àpilẹ̀kọ kejìdínlógún (18), àti European Convention on Human Rights, Àpilẹ̀kọ kẹsàn-án (9).