Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 15, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019​—Phoenix, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019​—Phoenix, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
  • Déètì: August 9 sí 11, 2019

  • Ibi Tó Ti Wáyé: Chase Field ní Phoenix, Arizona, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

  • Èdè: Gẹ̀ẹ́sì

  • Àwọn Tó Wá: 40,237

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 352

  • Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 5,000

  • Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Pè: Australasia, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Kánádà, Central Europe, Chile, Faransé, Gíríìsì, Íńdíà, Ítálì, Kòríà, Micronesia, Scandinavia, Sri Lanka, Tahiti, Thailand, Trinidad and Tobago, Tọ́kì

  • Ìrírí: Steve Moore tó jẹ́ ààrẹ àti Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Visit Phoenix, ló bá wa ṣètò ibi tá a ti ṣe àpéjọ náà, àwọn òtẹ́ẹ̀lì àti ibi ìgbafẹ́ tá a ṣeré lọ ní ìlú Phoenix, ó sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ gan-an tí mo ti ń ṣiṣẹ́ yìí, àmọ́ àpéjọ yín ló ṣì wà létòletò jù látìgbà tí mo ti ń ṣiṣẹ́ yìí. Inú mi dùn pé a jọ ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ ṣèlérí pé ẹ máa jẹ́ kí pápá ìṣeré yìí wà ní mímọ́ kẹ́ ẹ tó kúrò, kò sẹ́ni tó sọ bẹ́ẹ̀ rí, àfẹ̀yin nìkan.”

 

Wọ́n ń kí àwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè káàbọ̀ nígbà tí wọ́n dé Pápákọ̀ Òfuurufú Sky Harbor ní ìlú Phoenix

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin láti ìlú Phoenix ti ṣe tán láti kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí ọ̀kan lára òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ṣètò fún wọn

Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń fayọ̀ kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí Gbọ̀ngàn Chase Field láàárọ̀ Friday

Àwọn àlejò ń fetí sí ọ̀rọ̀ tó ń lọ lọ́wọ́, àwọn kan lára wọn wọ aṣọ ìbílẹ̀

Ẹni méjì lára ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti méjìléláàádọ́ta (352) àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ṣèrìbọmi

Arákùnrin Samuel Herd, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àsọyé tó kẹ́yìn lọ́jọ́ kejì àpéjọ náà

Àwọn àlejò ń ya fọ́tò nígbà tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí ọgbà kan

Àwọn arákùnrin wa ń wa ọkọ̀ tí wọ́n ń fi ẹṣin fà, wọ́n fi ń sọ ìtàn ìlú kan lápá Ìwọ̀ Oòrùn Amẹ́ríkà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún

Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó wá ṣèbẹ̀wò wá sórí pápá nígbà tí wọ́n parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday