Jóòbù 1:1-22

  • Ìwà títọ́ Jóòbù àti ọrọ̀ rẹ̀ (1-5)

  • Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù (6-12)

  • Jóòbù pàdánù ohun ìní rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ (13-19)

  • Jóòbù ò dá Ọlọ́run lẹ́bi (20-22)

1  Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Úsì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jóòbù.*+ Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni; ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.+  Ó bí ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta.  Ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ràkúnmí, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) màlúù* àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ó tún ní àwọn ìránṣẹ́ tó pọ̀ gan-an débi pé òun ló wá lọ́lá jù lọ nínú gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn.  Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń se àsè ní ilé wọn lọ́jọ́ tó bá yàn.* Wọ́n máa ń pe àwọn arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé kí wọ́n wá bá wọn jẹ, kí wọ́n sì jọ mu.  Tí àwọn ọjọ́ tí wọ́n ń jẹ àsè bá ti parí, Jóòbù máa ń ránṣẹ́ sí wọn kó lè sọ wọ́n di mímọ́. Ó máa dìde ní àárọ̀ kùtù, á sì rú ẹbọ sísun+ torí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Torí Jóòbù máa ń sọ pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti bú Ọlọ́run nínú ọkàn wọn.” Ohun tí Jóòbù máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà nìyẹn.+  Ó wá di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ ń wọlé láti dúró níwájú Jèhófà,+ Sátánì+ náà sì wọlé sáàárín wọn.+  Jèhófà bi Sátánì pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Látinú ayé, mo lọ káàkiri, mo sì rìn káàkiri nínú rẹ̀.”+  Jèhófà sì bi Sátánì pé: “Ṣé o ti kíyè sí* Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sí ẹni tó dà bí rẹ̀ ní ayé. Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.”  Ni Sátánì bá dá Jèhófà lóhùn pé: “Ṣé lásán ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run ni?+ 10  Ṣebí o ti ṣe ọgbà yí i ká láti dáàbò bo òun,+ ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní? O ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,+ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sì ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà. 11  Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.” 12  Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Gbogbo ohun tó ní wà ní ọwọ́ rẹ.* Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan ọkùnrin náà fúnra rẹ̀!” Ni Sátánì bá jáde kúrò níwájú* Jèhófà.+ 13  Ní ọjọ́ tí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Jóòbù ń jẹun, tí wọ́n sì ń mu wáìnì ní ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà tó jẹ́ ọkùnrin,+ 14  ìránṣẹ́ kan wá bá Jóòbù, ó sì sọ pé: “Àwọn màlúù ń túlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, 15  ni àwọn Sábéà bá gbógun dé, wọ́n kó wọn, wọ́n sì fi idà pa àwọn ìránṣẹ́. Èmi nìkan ló yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.” 16  Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹlòmíì dé, ó sì sọ pé: “Iná ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá* láti ọ̀run, ó bọ́ sáàárín àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́, ó sì jó wọn run! Èmi nìkan ló yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.” 17  Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹlòmíì dé, ó sì sọ pé: “Àwọn ará Kálídíà+ pín ara wọn sí àwùjọ mẹ́ta, wọ́n ya bo àwọn ràkúnmí, wọ́n sì kó wọn, wọ́n wá fi idà pa àwọn ìránṣẹ́. Èmi nìkan ni mo yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.” 18  Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹlòmíì tún dé, ó sì sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ń jẹun, wọ́n sì ń mu wáìnì ní ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà tó jẹ́ ọkùnrin. 19  Ni ìjì tó lágbára bá fẹ́ wá lójijì láti aginjù, ó fẹ́ lu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé náà, ilé náà sì wó lu àwọn ọmọ náà, wọ́n sì kú. Èmi nìkan ló yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.” 20  Ni Jóòbù bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó gé irun orí rẹ̀; ó wólẹ̀, ó sì forí balẹ̀, 21  ó wá sọ pé: “Ìhòòhò ni mo jáde látinú ikùn ìyá mi,Ìhòòhò ni màá sì pa dà.+ Jèhófà ti fúnni,+ Jèhófà sì ti gbà á. Ká máa yin orúkọ Jèhófà títí lọ.” 22  Nínú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jóòbù ò dẹ́ṣẹ̀, kò sì fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó ṣe ohun tí kò dáa.*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Aláìlẹ́bi àti adúróṣinṣin.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ohun Ìkórìíra.”
Ní Héb., “màlúù méjì-méjì lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún.”
Ní Héb., “abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Tàbí “ní ilé ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́jọ́ tó bá yí kàn án.”
Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.
Ní Héb., “fi ọkàn rẹ sí.”
Tàbí “Aláìlẹ́bi àti adúróṣinṣin.”
Tàbí “ní ìkáwọ́ rẹ.”
Ní Héb., “ní ojú.”
Tàbí kó jẹ́, “Mànàmáná wá.”
Tàbí “kò sì ka ohunkóhun tí kò tọ́ sí Ọlọ́run lọ́rùn.”