Jóòbù 17:1-16
17 “Ìbànújẹ́ ti bá ẹ̀mí mi, àwọn ọjọ́ mi ti dópin;Itẹ́ òkú ń retí mi.+
2 Àwọn tó ń fini ṣe yẹ̀yẹ́ yí mi ká,+Àfi kí ojú mi máa wo* ìwà ọ̀tẹ̀ wọn.
3 Jọ̀ọ́, gba ohun tí mo fi ṣe ìdúró, kí o sì tọ́jú rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ.
Ta ló tún máa bọ̀ mí lọ́wọ́, tó sì máa dúró fún mi?+
4 Torí o ò jẹ́ kí ọkàn wọn ní òye;+Ìdí nìyẹn tí o kò fi gbé wọn ga.
5 Ó lè fẹ́ kí òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pín in,Síbẹ̀, ojú àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣú.
6 Ó ti sọ mí di ẹni ẹ̀gàn* láàárín àwọn èèyàn,+Tí mo fi di ẹni tí wọ́n ń tutọ́ sí lójú.+
7 Ìrora ti sọ ojú mi di bàìbàì,+Òjìji sì ni gbogbo apá àti ẹsẹ̀ mi.
8 Àwọn olóòótọ́ ń wo èyí tìyanutìyanu,Ọkàn aláìṣẹ̀ ò sì balẹ̀ torí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run.*
9 Olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ rárá,+Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.+
10 Àmọ́ gbogbo yín tún lè wá máa ro ẹjọ́ yín,Torí mi ò rí ọlọ́gbọ́n kankan nínú yín.+
11 Àwọn ọjọ́ mi ti dópin;+Àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe, àwọn ohun tí ọkàn mi fẹ́, ti já sí asán.+
12 Wọ́n ń sọ òru di ọ̀sán,Wọ́n ń sọ pé, ‘Ó ní láti jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ wà nítòsí torí òkùnkùn ṣú.’
13 Tí mo bá dúró, Isà Òkú* máa di ilé mi;+Màá tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.+
14 Màá ké pe ihò*+ pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi!’
Àti ìdin pé, ‘Ìyá mi àti arábìnrin mi!’
15 Ibo wá ni ìrètí mi+ wà?
Ta ló lè bá mi rí ìrètí?
16 Ó* máa sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àwọn ẹnubodè Isà Òkú* tí wọ́n tì paTí gbogbo wa bá jọ sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú iyẹ̀pẹ̀.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “kí n tẹjú mọ́.”
^ Ní Héb., “àfipòwe.”
^ Tàbí “apẹ̀yìndà.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “sàréè.”
^ Ìyẹn, ìrètí mi.
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.