Nọ́ńbà 17:1-13

  • Ọ̀pá Áárónì tó rúwé jẹ́ àmì (1-13)

17  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì gba ọ̀pá kan ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, lọ́wọ́ ìjòyè agbo ilé+ kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ ọ̀pá méjìlá (12). Kí o kọ orúkọ kálukú sára ọ̀pá rẹ̀.  Kí o kọ orúkọ Áárónì sára ọ̀pá Léfì, torí pé olórí agbo ilé kọ̀ọ̀kan ló ni ọ̀pá kọ̀ọ̀kan.  Kó àwọn ọ̀pá náà lọ sínú àgọ́ ìpàdé níwájú Ẹ̀rí,+ níbi tí mo ti máa ń pàdé yín.+  Ẹni tí ọ̀pá rẹ̀ bá rúwé* ni ẹni tí mo yàn,+ màá sì pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nu mọ́ kí wọ́n má bàa kùn sí mi+ mọ́, bí wọ́n ṣe ń kùn sí ẹ̀yin náà.”+  Mósè wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, gbogbo ìjòyè wọn sì fún un ní ọ̀pá, ọ̀pá kan fún ìjòyè agbo ilé kọ̀ọ̀kan, ó jẹ́ ọ̀pá méjìlá (12), ọ̀pá Áárónì sì wà lára àwọn ọ̀pá náà.  Mósè wá kó àwọn ọ̀pá náà síwájú Jèhófà nínú àgọ́ Ẹ̀rí.  Nígbà tí Mósè wọnú àgọ́ Ẹ̀rí lọ́jọ́ kejì, wò ó! ọ̀pá Áárónì tó fi ṣojú fún ilé Léfì ti rúwé,* ó hù, ó yọ òdòdó, àwọn èso álímọ́ńdì tó ti pọ́n sì yọ lórí rẹ̀.  Mósè wá kó gbogbo ọ̀pá náà kúrò níwájú Jèhófà lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n wò ó, kálukú sì mú ọ̀pá tirẹ̀. 10  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Dá ọ̀pá+ Áárónì pa dà síwájú Ẹ̀rí, kó máa wà níbẹ̀, kó lè jẹ́ àmì+ fún àwọn ọmọ ọlọ̀tẹ̀,+ kí wọ́n má bàa kùn sí mi mọ́, kí wọ́n má bàa kú.” 11  Lójú ẹsẹ̀, Mósè ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. 12  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sọ fún Mósè pé: “A máa kú báyìí, ó dájú pé a máa ṣègbé, gbogbo wa la máa ṣègbé! 13  Kódà, ẹnikẹ́ni tó bá sún mọ́ àgọ́ ìjọsìn Jèhófà máa kú!+ Ṣé bí gbogbo wa ṣe máa kú nìyẹn?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “rudi.”
Tàbí “rudi.”