Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Ohun Táwọn Èèyàn Fi Ń Jọ́sìn?

Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Ohun Táwọn Èèyàn Fi Ń Jọ́sìn?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Ohun Táwọn Èèyàn Fi Ń Jọ́sìn?

Àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, Híńdù, Ìsìláàmù, ẹ̀sìn àwọn Júù, ẹ̀sìn Kátólíìkì àtàwọn ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn ayé, sábà máa ń lo ìlẹ̀kẹ̀ àtàwọn nǹkan míì tó ṣe é rí nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Torí náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé káàkiri ayé ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ti gbà pé, lílo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ káwọn sún mọ́ Ọlọ́run, káwọn rí ojú rere rẹ̀, tàbí káwọn rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Kí ni Bíbélì fi kọ́ni nípa èyí?

LÍLO àwọn ohun kan láti fi gbàdúrà kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, níbi tí ìlú Nínéfè ìgbàanì wà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀, The Catholic Encyclopedia sọ pé àwọn awalẹ̀pìtàn hú “ère àwọn obìnrin tó ní ìyẹ́ apá méjì tí wọ́n ń gbàdúrà níwájú igi mímọ́ kan jáde; ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà sì wà lọ́wọ́ [òsì] wọn.”

Kí ni wọ́n máa ń fi àwọn ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà ṣe? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ pé: “Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti fẹ́ gba àwọn àdúrà kan ní àgbàtúngbà, wọ́n sábà máa ń kọ ọ̀rọ̀ àdúrà náà sára ohun kan tó ṣeé yí, èyí sì máa mú kí àwítúnwí náà yára kánkán ju fífi ọmọọ̀ka ka ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà lọ.”

Lílò tí wọ́n ń lo àdúrà tí wọ́n kọ sára ohun tí wọ́n máa ń yí yìí tún máa ń mú kó túbọ̀ rọrùn fún wọ́n láti ṣe àwítúnwí. Wọ́n ka fífi ọwọ́, atẹ́gùn, omi tàbí iná mànàmáná yí i sí gbígbàdúrà. Wọ́n sábà máa ń lo ohun tí wọ́n ń yí yìí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ wúre, ìyẹn tí wọ́n bá fẹ́ kàn sáwọn ẹ̀mí àìrí. Ẹ jẹ́ ká wo ojú tí Ọlọ́run fi ń wo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.

“Má Ṣe Sọ Ohun Kan Náà ní Àsọtúnsọ”

Jésù Kristi tọ́pọ̀ èèyàn tí kì í tiẹ̀ ṣe Kristẹni mọ̀ sí wòlíì Ọlọ́run sọ ojú tí Ẹlẹ́dàá fi ń wo sísọ àsọtúnsọ nínú àdúrà, ó ní: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.” aMátíù 6:7.

Nítorí náà, tí Ọlọ́run kò bá tẹ́wọ́ gba sísọ “ohun kan náà ní àsọtúnsọ,” ṣé yóò wá tẹ́wọ́ gba lílo àwọn ohun kan láti fi gbàdúrà àgbàtúngbà? Bákan náà, Bíbélì kò sọ pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run èyíkéyìí lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, ohun tí wọ́n kọ àdúrà sí lára tàbí ohunkóhun mìíràn nínú ìjọsìn. A óò túbọ̀ wá mọ ìdí tí kò fi yẹ ká máa lo ohun kan láti fi gbàdúrà nígbà tá a bá mọ ohun ti àdúrà jẹ́ àti ìdí tá a fi ń gbàdúrà.

Àdúrà Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́

Nínú Àdúrà Olúwa tí Jésù gbà, ó pe Ọlọ́run ní “Baba Wa.” Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa kì í ṣe ẹni tí kò ṣeé sún mọ́ tàbí ẹ̀mí àìrí kan tó jẹ́ pé ọfọ̀, ètùtù tàbí èdè àpètúnpè ni wọ́n á máa fi tù ú lójú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Baba onífẹ̀ẹ́ ni, ó ń fẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, káwa náà sì nífẹ̀ẹ́ òun. Jésù sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòhánù 14:31) Nílẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì, wòlíì kan sọ pé: “Wàyí o, Jèhófà, ìwọ ni Baba wa.”—Aísáyà 64:8.

Báwo la ṣe lè sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Baba wa ọ̀run? (Jákọ́bù 4:8) Bó ṣe máa ń rí nínú àjọṣe àwa àtàwọn ẹlòmíì, à ń sún mọ́ Ọlọ́run nípa sísọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un, òun náà sì máa ń dá wa lóhùn. Bá a bá ń ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ńṣe ló máa ń dà bí ìgbà tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń bá wa sọ̀rọ̀, torí pé ibẹ̀ ló ti ń jẹ́ ká rí àwọn ohun tó ti ṣe, ànímọ́ rẹ̀ àtohun tó fẹ́ ṣe fún wa. (2 Tímótì 3:16) Àwa náà sì máa ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà. Àmọ́ ṣá o, irú àdúrà bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó tọkàn wá, ká gbà á tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kó má sì jẹ́ àkọ́sórí.

Gbé àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò: Nínú ìdílé ti àlááfíà wà, báwo lọmọ tórí ẹ̀ pé á ṣe máa bá àwọn òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀? Ṣé ọ̀rọ̀ kan náà láá máa sọ ṣáá, kódà kó tiẹ̀ máa fi ohun èèlò kan ka iye ìgbà tó ti sọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání láá máa sọ, á sì máa sọ ọ́ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, látọkànwá.

Bó ṣe yẹ kí àdúrà wa sí Ọlọ́run náà rí nìyẹn. Ká sòótọ́, gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn la lè bá Ọlọ́run sọ. Ìwé Fílípì 4:6, 7 sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run . . . yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.” Òótọ́ ni pé tí nǹkan kan bá ń jẹ wá lọ́kàn, a lè máa gbàdúrà nípa rẹ̀ léraléra. Àmọ́ ìyẹn yàtọ̀ sí sísọ àsọtúnsọ.—Mátíù 7:7-11.

Ọ̀pọ̀ àdúrà tí Ọlọ́run gbọ́ ló wà nínú Bíbélì, tó fi mọ́ àwọn sáàmù tàbí àwọn orin, àtàwọn àdúrà tí Jésù fúnra rẹ̀ gbà. b (Àwọn àkọlé Sáàmù 17 àti 86; Lúùkù 10:21, 22; 22:40-44) A lè rí àdúrà Jésù nínú ìwé Jòhánù orí 17. Wá àyè díẹ̀ láti kà á. Bó o ti ń kà á, wo bí Jésù ṣe tú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde fún Ọlọ́run. Kó o tún wo bí àdúrà yẹn kò ṣe jẹ́ ti onímọtara-ẹni nìkan, tó sì fi hàn bí ìfẹ́ tó ní sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ó ní: “Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn . . . nítorí ẹni burúkú náà,” Sátánì.—Jòhánù 17:11, 15.

Ǹjẹ́ àdúrà tí Jésù gbà fi hàn pé Ọlọrun ò ṣeé sún mọ́ tàbí pé àdúrà àkọ́sórí ló ń gbà? Rárá o! Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere nìyẹn jẹ́ fún wa! Dájúdájú gbogbo àwọn tó bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run ló gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. Ohun tí wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀ yóò mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọn yóò sì kọ àwọn ààtò ẹ̀sìn àtàwọn àṣà míì tí Ọlọ́run kò fẹ́ sílẹ̀. Jèhófà sọ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Èmi yóò sì jẹ́ baba yín, ẹ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi.”—2 Kọ́ríńtì 6:17, 18.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú Àdúrà Olúwa, Jésù kò sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà yìí,” torí ìyẹn máa ta ko ohun tó ti sọ ṣáájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí.” (Mátíù 6:9-13) Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Bí àdúrà náà ṣe fi hàn, a gbọ́dọ̀ máa fi ohun tó bá jẹ mọ́ ìjọsin Ọlọ́run ṣáájú àwọn ohun tara.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ sáàmù lórin, síbẹ̀ wọn ò sọ àsọtúnsọ bí àdúrà àkọ́sórí, wọn ò sì lò ó nígbà àwọn ayẹyẹ ìsìn níbi tí wọ́n ti ń lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà tàbí àdúrà tí wọ́n kọ sára nǹkan.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ṣé ohun tí Jésù sọ nípa àsọtúnsọ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú lílo àwọn ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà àti àdúrà tí wọ́n kọ sára nǹkan?—Mátíù 6:7.

◼ Kí ló yẹ kí àdúrà wa fi hàn nípa irú ojú tá a fi ń wo Ọlọ́run?—Aísáyà 64:8.

◼ Tá a bá kọ àwọn ẹ̀kọ́ èké sílẹ̀ irú ojú wo ni Ọlọ́run á máa fi wò wá?—2 Kọ́ríńtì 6:17, 18.