KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?
KÍ LO KÀ SÍ OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?
Kí ni ìwọ fúnra rẹ kà sí àṣeyọrí? Ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ yìí ná, kó o lè mọ̀.
Èwo nínú àwọn mẹ́rin yìí lo lè so pé ó ṣàṣeyọrí ní ti gidi?
-
ADÉ
Oníṣòwò ni Adé. Ọmọlúwàbí ni, kì í ṣe ọ̀lẹ, ó sì mọyì àwọn èèyàn. Òwò tó ń ṣe ti búrẹ́kẹ́, torí náà, nǹkan ṣẹnuure fún òun àti ìdílé rẹ̀.
-
BÁYỌ̀
Oníṣòwò lòun náà, àmọ́ ó rí towó ṣe ju Adé lọ. Ó kàn jẹ́ pé Báyọ̀ ti di ẹrú iṣẹ́ kó bàa lè yọrí ọlá ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, èyí sì ti dá onírúurú àìsàn sí i lára.
-
KẸ́MI
Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama ni Kẹ́mi. Ó já fáfá, ó sì kúndùn kó máa kàwé. Torí náà, ó máa ń yege nínú ìdánwò rẹ̀.
-
MOPÉ
Mopé máa ń gba máàkì tó pọ̀ ju ti Kẹ́mi lọ, gbogbo ìgbà sì lorúkọ rẹ̀ máa ń wà lára àwọn to fakọyọ ní kíláàsì. Ṣùgbọ́n ó máa ń jíwèé wò nínú ìdánwò, kò sì fi gbogbo ara gbádùn kó máa kàwé.
Àwọn wo lò rò pé ó ṣàṣeyọrí ní ti gidi? Tó bá jẹ́ pé Báyọ̀ àti Mopé lo mú àbí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, a jẹ́ pé bí wọ́n ṣe lowó tó tàbí bí máàkì wọn ṣe pọ̀ tó lo fi díwọ̀n àṣeyọrí wọn láìka ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà.
Àmọ́ bó bá jẹ́ pé Adé àti Kẹ́mi lo yàn, èrò rẹ tọ̀nà, torí pé ìwà wọn àti ọwọ́ tí wọ́n fi mú iṣẹ́ lo fi díwọ̀n àṣeyọrí wọn. Ó ṣe tán, gbogbo ohun tó ń dán kọ́ ni wúrà. Tá a bá wo ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, àá rídìí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ:
-
Èwo lo rò pé ó máa ṣe Kẹ́mi làǹfààní títí dọjọ́ alẹ́? Kó gba máàkì tó pọ̀ ni àbí kó mọ̀wé rẹ̀ dójú àmì?
-
Kí lo rò pé ó máa ṣe àwọn ọmọ Adé láǹfààní jù? Kí wọ́n ní gbogbo nǹkan amáyédẹrùn ni àbí kí bàbá wọn máa lo ojúlówó àkókó pẹ̀lú wọn?
Kókó ọ̀rọ̀ ni pé: Gbogbo ohun tó ń dán lọmọ aráyé kà sí àṣeyọrí; àmọ́ ojúlówó àṣeyọrí ju bẹ́ẹ̀ lọ, ó sábà máa ń dá lé àwọn ìwà àtàtà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.