Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ Bó O Ṣe Lè Dárí Ji Aya Tàbí Ọkọ Rẹ

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ Bó O Ṣe Lè Dárí Ji Aya Tàbí Ọkọ Rẹ

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Tí aya tàbí ọkọ rẹ bá sọ̀rọ̀ burúkú sí ẹ tàbí ṣe nǹkan kan tó dùn ẹ́, ọ̀rọ̀ náà lè máà kúrò lọ́kàn bọ̀rọ̀ tàbí kó dùn ẹ́ débi pé tó o bá ti rí i báyìí, ńṣe ni inú á máa bí ẹ. Ìfẹ́ tó o ní sí i lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣá, á wá dà bíi pé o kàn ń fara da ìgbéyàwó tí kò sífẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀. Èrò yẹn gan-an lásán lè múnú bí ẹ.

Má bọkàn jẹ́, nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó o mọ àwọn nǹkan kan nípa gbígbin ìbínú sọ́kàn.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Tó o bá ń gbin ìbínú sọ́kàn, ńṣe lò ń dí ìtẹ̀síwájú ìgbéyàwó rẹ lọ́wọ́

Tọkọtaya tó bá ń gbin ìbínú sọ́kàn fẹ́ da ìgbéyàwó wọn rú ni. Ìdí ni pé òdìkejì gbáà ló jẹ́ sí àwọn ìwà tó máa ń mú kí ìgbéyàwó tọ́jọ́. Ìwà bí ìfẹ́, fífi ọkàn tán ara ẹni, àti ìṣọ̀kan tí kì í ṣá. Torí náà, kò yẹ kéèyàn máa wá ṣàwáwí pé ohun tẹ́nì kejì wa ṣe ló mú wa bínú, ó yẹ ká mọ̀ pé gbígbin ìbínú sọ́kàn yẹn gan-an ni ìṣòro tó ń da ìgbéyàwó rú. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: ‘Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú kúrò lọ́dọ̀ yín.’—Éfésù 4:31.

Ẹni tó bá ń gbin ìbínú sọ́kàn, ń ṣe ara ẹ léṣe. Tó o bá ń gbin ìbínú sọ́kàn, o dà bí ẹni tó gba ara rẹ̀ lábàrá tó wá ń retí pé kẹ́nì kejì máa jẹ̀rora. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Mark Sichel sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Healing From Family Rifts, pé: “Ibi tọ́rọ̀ náà burú sí ni pé ẹni tó ò ń bínú sí tiẹ̀ lè má rí ọ̀rọ̀ náà rò, kó sì máa gbádùn ìgbésí ayé tiẹ̀ nìṣó láì mọ̀ pé ẹnì ń kan bínú sí òun. Á wá di pé ìrora ọkàn tí ìwọ tó ò ń bínú máa jẹ́ á ju tẹni tí ò ń bínú sí lọ.”

Tó o bá ń gbin ìbínú sọ́kàn, o dà bí ẹni tó gba ara rẹ̀ lábàrá tó wá ń retí pé kẹ́nì kejì máa jẹ̀rora

Ìwọ lo máa pinnu bóyá o fẹ́ kọ́rọ̀ náà tán nínú ẹ. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà bẹ́ẹ̀ ṣá. Àwọn míì máa ń ṣàròyé pé ‘ìwà ọkọ tàbí aya wọn ló mú káwọn bínú.’ Ńṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ ń pe àfiyèsí sí ohun tí o kò lè ṣe nǹkan kan sí, ìyẹn ìwà tẹ́nì náà hù sí ẹ. Ì bá dáa kó o máa rántí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́.” (Gálátíà 6:4) Ká má gbàgbé pé a ò le pinnu bó ṣe yẹ kẹ́nì kan sọ̀rọ̀ sí wa, àmọ́ a lè pinnu bá a ṣe fẹ́ kọ́rọ̀ náà rí lára wa. Torí náà dídi ẹni náà sínú kò lè yanjú ìṣòro.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Gba ẹ̀bi rẹ lẹ́bi. Ká má parọ́, ó rọrùn láti nàka sí ẹnì kejì pé òun ló jẹ̀bi. Ṣùgbọ́n rántí ohun tá a sọ lẹ́ẹ̀kan pé ìwọ lo máa pinnu bóyá wà á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tán nínú ẹ, ìwọ náà lo tún máa pinnu bóyá wàá dárí ji ẹnì kejì rẹ. Ṣùgbọ́n ó dára tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ẹ nínú ìbínú.’ (Éfésù 4:26) Tó o bá lẹ́mìí ìdáríjì, ó dájú pé wàá lè fọkàn balẹ̀ yanjú ìṣòro tó bá jẹyọ nínú ìgbéyàwó rẹ.—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 3:13.

Fara balẹ̀ yẹ ara rẹ wò. Bíbélì sọ pé àwọn kan máa ń “fi ara [wọn] fún ìbínú,” wọ́n tún máa ń “fi ara [wọn] fún ìhónú.” (Òwe 29:22) Ṣé kì í ṣe ìwọ ni ọ̀rọ̀ yẹn ń bá wí? Ó yẹ kó o bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń gbin ìbínú sọ́kàn? Ṣé mo máa ń tètè bínú? Ṣé mo máa ń sọ ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan di bàbàrà?’ Rántí ohun tí Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ọ̀ràn, ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.” (Òwe 17:9; Oníwàásù 7:9) Tó ò bá ṣọ́ra, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó tìẹ náà. Torí náà, tó o bá jẹ́ ẹni tó ń gbin ìbínú sọ́kàn, á dáa kó o bi ara rẹ pé: ‘Kí ni mo lè ṣe tí màá fi máa mú sùúrù fún ọkọ tàbí aya mi?’—Ìlànà Bíbélì: 1 Pétérù 4:8.

Ọ̀ràn tó bá ṣe pàtàkì ni kẹ́ ẹ jókòó sọ. Bíbélì sọ pé: “Ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníwàásù 3:7) Kì í ṣe gbogbo ohun tó bá bí ẹ́ nínú náà ni wàá tìtorí ẹ̀ pe ẹnì kejì ẹ jókòó lé lórí; ìgbà míì wà tí wàá kàn ‘sọ ohun tó o ní í sọ ní ọkàn-àyà rẹ . . . , kó o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Sáàmù 4:4) Tó bá tiẹ̀ gba pé kẹ́ ẹ bá ara yín sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀, kì í ṣe ìgbà tára ẹ bá ń gbóná lọ́wọ́ ni wàá dá irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí atẹ́gùn àlàáfíà kọ́kọ́ fẹ́ sí ọ̀rọ̀ náà kẹ́ ẹ tó jókòó sọ ọ́. Ohun tí obìnrin kan tó jẹ́ Beatriz máa ń ṣe nìyẹn, ó ní: “Tí inú bá bí mi sí ohun kan tí ọkọ mi ṣe, mó máa ń kọ́kọ́ sapá láti fara balẹ̀ ná. Nígbà míì, màá wá rí i pé ohun tí mò ń bínú sí ò tó nǹkan, ìyẹn sì máa ń mú kó rọrùn fún mi láti fi ìrẹ̀lẹ̀ bá ọkọ mi sọ̀rọ̀.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 19:11.

Mọ ohun tó túmọ̀ sí láti “dárí jini.” Nínú Bíbélì, gbólóhùn tí wọ́n tú sí “dárí jini” jẹ mọ́ kéèyàn gbàgbé ohun kan pátápátá, kó jẹ́ kó tán nílẹ̀. Torí náà, kéèyàn dárí jini kò sọ pé kéèyàn ṣe bíi pé nǹkan kan ò ṣẹlẹ̀ tàbí kéèyàn fojú kéré ohun to ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí kéèyàn gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn pátápátá, torí pé ìbínú lè ṣàkóbá fún ìlera ẹni tàbí kó tiẹ̀ da ìgbéyàwó rú.