Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìgbéyàwó

Ohun Tó Lè Mú Kó O Ṣàṣeyọrí

Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ràn Yín Lọ́wọ́ Kí Ẹ Lè Jẹ́ Tọkọtaya Aláyọ̀

Ìbéèrè méjì wà tó rọrùn tó o lè bi ara ẹ tó máa jẹ́ kó o rí ohun tó o lè ṣe kí ìgbéyàwó ẹ lè túbọ̀ láyọ̀.

Báwo Ni Tọkọtaya Ṣe Lè Láyọ̀?

Àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì nípa bí tọkọtaya ṣe lè láyọ̀ wúlò gan-⁠an, torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó ṣètò ìgbéyàwó ló fún wa ni àwọn ìmọ̀ràn náà.

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀

Kí ni ọkọ, ìyàwó àtàwọn ọmọ lè ṣe táá mú kí ìdílé wọn láyọ̀?

Ìdílé Aláyọ̀​—Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

Ǹjẹ́ ó ń ṣe ẹ́ bíi pé alájọgbé lásán ni ìwọ àti ẹnì kejì rẹ?

Bó O Ṣe Lè Máa Ní Sùúrù

Tí èèyàn aláìpé méjì bá fẹ́ra wọn, oríṣiríṣi ìṣòro ló máa yọjú. Sùúrù ṣe pàtàkì kí ìdílé tó lè ṣàṣeyọrí.

Bó O Ṣe Lè Fi Ọ̀wọ̀ Hàn

Fífi ọ̀wọ̀ hàn nínú ìgbéyàwó kì í ṣe ohun téèyàn ń ṣé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ohun téèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà gbogbo ni. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ?

Ẹ Máa Fìfẹ́ Hàn Sí Ara Yín

Iṣẹ́, àtijẹ àtimu àtàwọn ìṣòro míì lè má jẹ́ kí tọkọtaya ráyè fún ara wọn mọ́. Kí làwọn tọkọtaya lè ṣe kí wọ́n lè máa fìfẹ́ hàn síra wọn bíi ti tẹ́lẹ̀?

Bó O Ṣe Lè Mọyì Ẹnì Kejì Rẹ

Tí ọkọ àti ìyàwó bá ń sapá láti kíyè sí àwọn ànímọ́ tó dáa tí ẹnì kejí wọn ní, àjọgbé wọn máa tura. Báwo lo ṣe lè jẹ́ ẹni tó máa ń fi ìmọrírì hàn?

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín

Báwo ni tọkọtaya ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara àwọn dénú? Wo àbá mẹ́rin tó dá lórí àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì.

Bí Ìfẹ́ Yín Ṣe Lè Jinlẹ̀ Sí I

Ṣé ìfẹ́ tó o ní fún ọkọ tàbí aya rẹ mú kí ìdílé yín dúró sán-ún?

Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín

Ṣé tí ẹnì kan bá ṣáà ti ń sá fún ìṣekúṣe, ó ti jẹ́ olóòótọ́ sí ẹnì kejì rẹ̀ nìyẹn?

Bí Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí

Ìṣòro tó máa ń wáyé nínú ìgbéyàwó téèyàn tún ṣe lè máà sí nínú ìgbéyàwó àkọ́kọ́. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè ṣàṣeyọrí?

Eyin Oko—E Mu Ki Ile Yin Tura

Idile kan le ma ni isoro jije mimu, sibe ki ara ma tu won.

Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀​—Ìfẹ́

Èèyàn máa láyọ̀ tí wọ́n bá ń fi ìfẹ́ hàn síni téèyàn sì ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmí ì.

Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ̀rọ̀ Nípa Ìgbéyàwó Láàárín Ọkùnrin àti Ọkùnrin Tàbí Láàárín Obìnrin àti Obìnrin?

Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ ló yẹ kò mọ̀ béèyàn ṣe lè ní ìgbéyàwó tó wà pẹ́ títí lọ, tó sì láyọ̀.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ju Ìyàwó Kan Lọ?

Ṣé Ọlọ́run ló dá àṣà kí ọkùnrin máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ sílẹ̀? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa kí ọkùnrin fẹ́ ju ìyàwó kan lọ.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó Àwọn Tí Kì í Ṣe Ẹ̀yà Kan Náà?

Wo àwọn ìlànà Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀yà àti ìgbéyàwó.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?

Ìlànà Bíbélì lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n máa bàa ní ìṣòro tàbí kí wọ́n lè borí rẹ̀.

Ṣé Ó Dìgbà Téèyàn Bá Lọ́kọ Tàbí Téèyàn Bá Láya Kó Tó Lè Láyọ̀?

Ṣé àwọn Kristẹni tí kò ṣègbeyàwó lè láyọ̀ ṣá? Bíbélì jẹ́ ká mọ ojú tó yẹ ká fi wo ìgbeyàwó àti àpẹẹrẹ àwọn tí kò gbéyàwó, síbẹ̀ tí wọ́n láyọ̀.

Ìṣòro àti Ojútùú

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ẹnì Kejì Ẹ Bá Hùwà Tó Ń Múnú Bí Ẹ

Dípò tí wàá fi jẹ́ kí ìwà tó ń múnú bí ẹ dá ìjà sílẹ̀, kọ́ bó o ṣe lè máa fi ojú tó yàtọ̀ wo nǹkan.

Fi Iṣẹ́ Sílẹ̀ “Síbi Iṣẹ́”

Àbá márùn-ún tí kò ní jẹ́ kí iṣẹ́ ṣèdíwọ́ fún ìgbéyàwó rẹ.

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn tí Wọ́n Ń Fìyà Jẹ Nínú Ilé

Mọ̀ pé ìwọ kọ́ lo lẹ̀bi, o ò sì dá wà.

Bí Ọkọ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Lílu Ìyàwó Rẹ̀

Báwo ni Bíbélì ṣe lè ran àwọn tó ń hùwà ipa lọ́wọ́ láti yí ìwà wọn pa da?

Bo O Se Le Ni Ajose To Daa Pelu Awon Ana Re

Ohun meta ti ko ni je ki isoro to o ni pelu awon ana re da wahala sile laarin iwo ati oko tabi iyawo re.

Bí Ẹ Ṣe Lè Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Ẹ̀yin Àtàwọn Mọ̀lẹ́bí Yín

O lè bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí rẹ, síbẹ̀ kí ìyẹn má da ìgbéyàwó rẹ rú.

Tí Èrò Yín Ò Bá Jọra

Tí tọkọtaya ò bá gbọ́ra wọn yé, báwo ni wọ́n ṣe lè yanjú ẹ̀, kí wọ́n sì wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn?

Tí Ọkọ Tàbí Aya Kan Bá Ń Wo Àwòrán Ìṣekúṣe

Báwo ni tọkọtaya ṣe lè ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí ọkọ lè jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe tó ti mọ́ ọn lára, kí wọ́n lè pa dà fọkàn tán ara wọn?

Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe Lè Tú Ìgbéyàwó Rẹ Ká

Àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́, ko o sì ṣe ohun táá jẹ́ kí àárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ̀ túbọ̀ gún régé.

Ìdílé Aláyọ̀​—Ìdáríjì

Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má gbójú fo àìpé ẹnì kejì rẹ?

Nígbà Tí Àwọn Ọmọ Bá Ti Kúrò Nílé

Kì í rọrùn rárá fún àwọn òbí kan tí àwọn ọmọ bá ti dàgbà tí wọ́n sì ti kúrò nílé. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó máa wáyé nígbà tó bá ti ku àwọn nìkan nínú ilé?

Nígbà tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀s

Wá ìrànlọ́wọ́ tó yẹ.

Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Owú Ò Fi Ní Dá Wàhálà Sílẹ̀ Láàárín Yín

Ìgbéyàwó ò lè láyọ̀ tí tọkọtaya bá ń fura síra wọn, tí wọn ò sì fọkàn tán ara wọn. Torí náà, kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa jowú láìnídìí?

Bí Ọ̀rẹ́ Ìwọ Àtẹnì Kan Bá Ti Ń Wọra Jù

Ṣé o máa ń sọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ lásán ni wá?’ Tó bá rí bẹ̀, ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kó o rí ìdí tí kò fi yẹ kí o ronú bẹ́ẹ̀.

Fífi Ara Sílẹ̀ àti Ìkọ̀sílẹ̀

Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ

Àwọn kan ronú pé táwọn bá kọ ara wọn sílẹ̀, ìyẹn á ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní. Àmọ́ ìwádìí fi hàn pé àkóbá ńlá ló máa ń ṣe.

Tí Ẹnì Kejì Rẹ Bá Ṣe Ìṣekúṣe, Ṣé Ayé Rẹ Ṣì Lè Dùn?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí ìtùnú nínú Ìwé Mímọ́ nígbà tí ẹni kejì wọn ṣe ìṣekúṣe.

Kí Ní Bíbélì Sọ Nípa Panṣágà

Ṣé panṣágà lè tú ìgbéyàwó ká?

Ǹjẹ́ Bíbélì Fàyè Gba Ìkọ̀sílẹ̀?

Kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fàyè gbà àti ohun tó kórìíra.

Bó O Ṣe Lè Máa Gbé Ayé Rẹ Lọ Lẹ́yìn Ìkọ̀sílẹ̀

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó ti kọ ara wọn sílẹ̀ ló máa ń rí i pé nǹkan le fún àwọn lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀ ju bí àwọn ṣe rò lọ. Àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì wúlò, á jẹ́ kó o lè kojú ìṣòro rẹ

Ojú Wo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ìkọ̀sílẹ̀?

Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ran àwọn tọkọtaya tó bá níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn lọ́wọ́? Ṣé ó di dandan káwọn alàgbà ìjọ fọwọ́ sí i tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bá fẹ́ kọ ìyàwó tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀?