Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

2 Ní Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run

2 Ní Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run

2 Ní Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run

“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.”—Jòhánù 17:3.

ÌDÍ TÓ FI ṢÒRO: Àwọn kan sọ pé kò sí Ọlọ́run. Àwọn míì gbà pé Ọlọ́run kì í ṣe ẹni gidi kan, pé agbára àìrí kan ni. Àwọn tó sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà tún ń fàwọn ẹ̀kọ́ tó ń ta kora kọ́ àwọn èèyàn nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀.

BÓ O ṢE LÈ ṢÀṢEYỌRÍ: Ohun kan téèyàn lè ṣe láti ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ni pé kó fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Róòmù 1:20) Tó o bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sáyé yìí, wàá kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ọgbọ́n àti agbára Ẹlẹ́dàá wa.—Sáàmù 104:24; Aísáyà 40:26.

Àmọ́ kéèyàn tó lè ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, kálukú wa gbọ́dọ̀ fúnra ẹ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn máa fi èrò tiwọn tì ẹ́ kiri bíi dọ̀bọ̀sìyẹsà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn láti ṣe rèé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn òkodoro òtítọ́ tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run.

Ọlọ́run lórúkọ. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà làwọn tó kọ Bíbélì lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ. Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló lo orúkọ yìí nínú ìwé Sáàmù 83:18, ó kà pé: ‘Kí àwọn ènìyàn kí ó lè mọ̀ pé ìwọ, orúkọ ẹnì kan ṣoṣo tí í jẹ́ Jèhófà, ìwọ ni Ọ̀gá ògo lórí ayé gbogbo.’—Bibeli Mimọ.

Jèhófà Ọlọ́run máa ń mọ ìwà àwa èèyàn lára. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, wọ́n máa ń ṣá àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó fún wọn tì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ń hù yìí “mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́,” kódà “ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”—Sáàmù 78:40, 41.

Jèhófà bìkítà fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mátíù 10:29-31.

Ọlọ́run kì í ṣojúsàájú tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀yà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Gíríìkì tó ń gbé ní Áténì pé, “láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” Ó tún sọ fún wọn pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:26, 27) Àpọ́sítélì Pétérù sì sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Àwọn kan ní “ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Tó o bá mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa Ọlọ́run, o ò ní gbà káwọn kan máa tàn ẹ́ jẹ, wàá sì lè “sún mọ́ Ọlọ́run.”—Jákọ́bù 4:8.

Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 1 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ọ̀kan lára ohun téèyàn lè ṣe láti ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ni pé kó fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Ọlọ́run dá