Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Ayé Yìí Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀tanú?

Ìgbà Wo Ni Ayé Yìí Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀tanú?

NÍ ÀÁDỌ́TA ọdún sẹ́yìn, ìyẹn ní August 28, 1963, ọ̀gá àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Martin Luther King, Kékeré, sọ pé òun ní ìrètí kan. Ìgbà tó ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó lókìkí jù lọ ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ yìí léraléra láti fi ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn yẹn sọ ìrètí tó ní, pé lọ́jọ́ kan kò ní sí ìwà ẹ̀tanú mọ́ nínú ayé yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Amẹ́ríkà ló ń bá sọ̀rọ̀ nígbà yẹn, àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló gbà pé òótọ́ lohun tó sọ.

Martin Luther King, Kékeré, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀tọ́ tí gbogbo èèyàn ní

Ní November 20, ọdún 1963, ìyẹn oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí Luther King sọ ọ̀rọ̀ yẹn, ó lé ní ọgọ́rùn-ún orílẹ̀-èdè tó fara mọ́ Òfin tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣe Láti Fòpin sí Onírúurú Ìwà Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Láàárín àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé gba àwọn àbádòfin míì wọlé. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ìbéèrè tó ṣì máa ń wà lọ́kàn wa ni pé, Kí ló ti wá jẹ́ àbájáde gbogbo kìràkìtà wọn?

Ní March 21, ọdún 2012, Ọ̀gbẹ́ni Ban Ki-moon tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àdéhùn àti àwọn nǹkan ajẹ́bíidán míì tó gbéṣẹ́ wà kárí ayé tí a lè lò láti fi mú kí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àìfẹ́ rí àjèjì sójú àti àìrára gba nǹkan sí kásẹ̀ nílẹ̀ tàbí kó má tiẹ̀ rú yọ rárá. Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ni ìyà ń jẹ kárí ayé torí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà.”

Kódà, ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti gbógun ti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti onírúurú ẹ̀tanú míì, ìbéèrè kan ṣì wà tó ń jà gùdù lọ́kàn àwọn èèyàn. Ìbéèrè náà ni pé: Ṣé ohun tí wọ́n ṣe yìí ti mú ẹ̀tanú tó ti jingíri lọ́kàn àwọn èèyàn kúrò pátápátá, àbí ṣe ló kàn ń mú kí àwọn èèyàn fi ẹ̀jẹ̀ sínú tutọ́ funfun jáde? Àwọn kan gbà pé irú ohun tí wọ́n ṣe yìí kàn lè dín kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kù láwùjọ ni, ṣùgbọ́n kò lè mú ẹ̀tanú kúrò pátápátá. Kí nìdí? Ìdí ni pé, téèyàn bá ń ṣe kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àwọn èèyàn á mọ̀, onítọ̀hún sì lè jìyà lábẹ́ òfin, àmọ́ ẹ̀tanú ní ín ṣe pẹ̀lú ohun tó wà lọ́kàn wa àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, èyí sì ń mú kó nira láti lè tètè wá nǹkan ṣe sí i.

Torí náà, tí ìwà ẹ̀tanú bá máa di ohun ìgbàgbé, kì í ṣe pé kéèyàn kàn paná ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà nìkan ni, àmọ́, ó gba pé kéèyàn ṣàtúnṣe sí irú ojú tó fi ń wo àwọn ẹ̀yà míì tàbí irú èrò tó ní nípa wọn. Ǹjẹ́ èyí ṣeé ṣe? Tó bá lè ṣeé ṣe, ọ̀nà wo la lè gbé e gbà? Ẹ jẹ́ ká wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn lè yí èrò tí wọ́n ní nípa àwọn ẹ̀yà kan pa dà, a sì tún máa mọ ohun tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

BÍBÉLÌ JẸ́ KÍ WỌ́N LÈ BORÍ Ẹ̀TANÚ

“Mi ò sí nínú ìgbèkùn ẹ̀tanú mọ́.”—Linda

Linda: Orílẹ̀-èdè South Africa ni wọ́n ti bí mi. Mo máa ń ka àwọn ọmọ ilẹ̀ South Africa tó bá jẹ́ aláwọ̀ dúdú sí púrúǹtù, èèyàn tí kò já mọ́ nǹkan kan, ẹni tí kò ṣeé fọkàn tán àti ẹrú àwọn aláwọ̀ funfun. Àṣé ìwà ẹ̀tanú ló wọ̀ mí lẹ́wù, tí mi ò sì fura rárá. Àmọ́ ìwà mi bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà nígbà ti mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú” àti pé ohun tó wà lọ́kàn wa ṣe pàtàkì sí i ju àwọ̀ tàbí èdè wa lọ. (Ìṣe 10:34, 35; Òwe 17:3) Ohun tí ìwé Fílípì 2:3 sọ jẹ́ kí n mọ̀ pé màá lè paná ẹ̀mí ẹ̀tanú lọ́kàn mi tí mo bá gbà pé gbogbo èèyàn lọ́lá jù mí lọ. Irú ìlànà Bíbélì tí mò ń tẹ̀ lé yìí ti jẹ́ kí n lè máa kó gbogbo èèyàn mọ́ra láìka àwọ̀ ara wọn sí. Ní báyìí, mi ò sí nínú ìgbèkùn ẹ̀tanú mọ́.

“Mo wá mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwa èèyàn.”—Michael

Michael: Àwọn ọmọ ilẹ̀ Ọsirélíà tó jẹ́ aláwọ̀ funfun ló pọ̀ jù níbi tí mo gbé dàgbà, torí náà mo dìídì kórìíra àwọn ọmọ ilẹ̀ Éṣíà tó wà níbẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn tó bá wá láti orílẹ̀-èdè Ṣáínà. Tí mo bá ń wa ọkọ̀ lọ, tí mo sì rí ẹnì kan tó rí bí ará ilẹ̀ Éṣíà, ṣe ni mo máa ń yí gíláàsì ọkọ̀ mi wálẹ̀ tí màá sì pariwo mọ́ ọn, mo lè sọ pé “Gba ìlú ẹ lọ, ìwọ ọmọ ilẹ̀ Éṣíà burúkú yìí!” Àmọ́ nígbà tó yá tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo wá mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwa èèyàn. Ó nífẹ̀ẹ́ wa, kì í wo ibi tá a ti wá tàbí bí a ṣe rí. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an débi pé ó mú kí n yí ìkórìíra tó wà lọ́kàn mi pa dà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó ya èmi fúnra mi lẹ́nu pé mó lè yára yí pa dà báyẹn. Ní báyìí, inú mi máa ń dùn láti bá oríṣiríṣi èèyàn láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ̀rọ̀ fàlàlà. Èyí ti mú kí èrò tí mo ní nípa ìgbésí ayé yí pa dà, mo sì ń láyọ̀.

“Mo yí èrò mi pa dà, mo sì wá àlàáfíà.”—Sandra

Sandra: Ọmọ ìlú Umunede ní ìpínlẹ̀ Delta, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni màmá mi. Àmọ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Edo ni bàbá mi, èdè Esan ni wọ́n sì ń sọ. Nítorí àṣà àti èdè wọn tó yàtọ̀ síra yìí, àwọn mọ̀lẹ́bí bàbá mi ṣe ẹ̀tanú tó le sí màmá mi títí tó fi kú. Èyí mú kí n jẹ́jẹ̀ẹ́ pé mi ò ní bá àwọn tó ń sọ èdè Esan da nǹkan kan pọ̀, mi ò sì ni fẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Edo láéláé. Àmọ́ èrò mi bẹ̀rẹ̀ sí í yàtọ̀ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níwọ̀n bí Bíbélì ti sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú àti pé inú rẹ̀ dùn sí ẹnikẹ́ni tó bá bẹ̀rù òun, báwo ni tèmi ṣe jẹ́ tí màá fi wá kórìíra àwọn kan torí ẹ̀yà wọn tàbí èdè wọn? Mo yí èrò mi pa dà, mo sì wá àlàáfíà láàárín èmi àti àwọn mọ̀lẹ́bí bàbá mi. Ìlànà Bíbélì tí mò ń tẹ̀ lé ti jẹ́ kí n láyọ̀, ó sì jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀. Ó tún jẹ́ kí èmi àti àwọn míì mọwọ́ ara wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ẹ̀yà wọn, èdè wọn, bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà tàbí orílẹ̀-èdè wọn yàtọ̀ sí tèmi. Kẹ́ ẹ sì wá wò ó, ọmọ ìpínlẹ̀ Edo ni ọkọ tí mo pa dà wá fẹ́, èdè Esan ló sì ń sọ!

Kí ló jẹ́ kí Bíbélì lè ran àwọn tí a mẹ́nu kàn yìí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìkórìíra àti ẹ̀tanú tó ti jinlẹ̀ lọ́kàn wọn tẹ́lẹ̀? Ìdí ni pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó lágbára láti yí ohun tí ẹnì kan bá ń rò nípa àwọn ẹlòmíì àti bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe máa ń rí lára rẹ̀ pa dà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ohun míì tó máa fòpin sí gbogbo ìwà ẹ̀tanú.

ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA FÒPIN SÍ GBOGBO Ẹ̀TANÚ

Ẹ̀kọ́ Bíbélì lè jẹ́ ká fa àwọn èrò tí kò tọ́ tí a ní nípa àwọn kan tu lọ́kàn wa tàbí kó mú ká kápá rẹ̀. Àwọn ohun méjì kan wà tó gbọ́dọ̀ kúrò kí ìwà ẹ̀tanú tó lè kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá. Nǹkan àkọ́kọ́ ni, ẹ̀ṣẹ̀ àti bí àwa èèyàn ṣe jẹ́ aláìpé. Bíbélì sọ òótọ́ ibẹ̀ pé: “Kò sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 8:46) Torí náà, kò sí bí a ṣe lè sa gbogbo ipá wa tó, ohun kan tó bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fínra nínú lọ́hùn-ún ló ń bá àwa náà fínra. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” (Róòmù 7:21) Lóòrèkóòrè, ọkàn àìpé wa máa ń fẹ́ pa dà sí “àwọn èrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,” èyí sì lè mú ká máa ṣe ẹ̀tanú.—Máàkù 7:21.

Ohun kejì ni ipa tí Sátánì Èṣù máa ń ní lórí wa. Bíbélì pè é ní “apànìyàn,” ó sì sọ pé ó ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 12:9) Èyí gan-an ló jẹ́ ká mọ ìdí tí ìwà ẹ̀tanú fi gbilẹ̀ àti ohun tó mú kápá àwọn èèyàn máà ká ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìpẹ̀yàrun àti àwọn ìṣòro míì tó ń wáyé nítorí ẹ̀yà, ẹ̀sìn àti àwùjọ tó yàtọ̀ síra káàkiri.

Nítorí náà, ká tó lè bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀tanú, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹran ara wa ẹlẹ́ṣẹ̀, a sì tún gbọ́dọ̀ bọ́ lọ́wọ́ ipa tí Sátánì Èṣù máa ń ní lórí wa. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn.

Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lọ́nà yìí: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú gbogbo àìṣẹ̀tọ́, títí kan ìwà ẹ̀tanú àti àìrára gba nǹkan sí kúrò pátápátá.

Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, Jésù Kristi máa “de” Sátánì tàbí kó ká a lọ́wọ́ kò pátápátá “kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.” (Ìṣípayá 20:2, 3) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, “ilẹ̀ ayé tuntun” tá a tún lè pè ní àwọn ẹ̀dà èèyàn máa wà, “òdodo yóò sì máa gbé” láàárín wọn. *2 Pétérù 3:13.

Ọlọ́run máa sọ àwọn olódodo èèyàn tí yòó máa gbé nígbà yẹn di ẹni pípé, wọ́n á sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 8:21) Àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run “kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun.” Kí nìdí? “Nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Nígbà yẹn, gbogbo aráyé máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n á sì máa hùwà tó dára bíi ti Ọlọ́run. Èyí ló máa fòpin sí gbogbo ẹ̀tanú, “nítorí kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—Róòmù 2:11.

^ ìpínrọ̀ 17 Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tó máa tó gbé ṣe láìpẹ́, wo orí 3, 8, àti 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.