Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

Ibo ni gbogbo ẹ̀yà tó wà láyé ti wá?

“Ádámù pe orúkọ aya rẹ̀ ní Éfà, nítorí pé òun ni yóò di ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:20.

OHUN TÁWỌN Ọ̀MỌ̀RÀN SỌ

Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ àti Àṣà Ìbílẹ̀ (UNESCO) sọ pé: “Látinú ẹ̀yà kan ṣoṣo ni gbogbo èèyàn pátá ti wá, ìdílé kan náà sì ni gbogbo wa.”—Òfin Nípa Ẹ̀yà Ìran àti Ẹ̀tanú, 1978.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run dá èèyàn méjì tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ádámù àti Éfà, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki e si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28, Bibeli Mimọ.) Torí náà, Ádámù àti Éfà ni bàbá àti ìyá gbogbo aráyé. Nígbà tó di àkókò kan, Ìkún-omi pa èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó wà láyé, tọkọtaya mẹ́rin nìkan ló ṣẹ́ kù, ìyẹn Nóà àti ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin Nóà mẹ́ta àtàwọn ìyàwó wọn. Bíbélì fi yé wa pé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọkùnrin Nóà ni gbogbo àwa èèyàn ti ṣẹ̀ wá.—Jẹ́nẹ́sísì 9:18, 19.

Ṣé ẹ̀yà kan dára ju òmíràn lọ?

“Láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.”—Ìṣe 17:26.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ní ọ̀rúndún ogún, àwọn ẹgbẹ́ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kan kó ara wọn jọ. Bí àpẹẹrẹ, ìjọba Násì sọ nígbà yẹn pé ẹ̀rí wà pé ẹ̀yà kan dára ju òmíràn lọ. Àmọ́, àjọ UNESCO sọ nínú ìwé tá a ti fa ọ̀rọ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan pé, “ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo ìran èèyàn wà níṣọ̀kan àti pé ohun tó pọ̀ jù lọ ni gbogbo èèyàn fi jọra, torí náà ẹ̀yà kan ò dára ju òmíràn lọ.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìṣe 10:34, 35 sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Fún ìdí yìí, kò ní dáa rárá kẹ́nì kan ka ẹ̀yà kan sí pàtàkì ju òmíràn lọ.

Jésù jẹ́ ká mọ ojú tó yẹ káwọn Kristẹni máa fi wo ara wọn nígbà tó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.” (Mátíù 23:8) Ó tún gbàdúrà pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wà níṣọ̀kan “kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan,” kí wọ́n má ṣe ya ara wọn sọ́tọ̀. —Jòhánù 17:20-23; 1 Kọ́ríńtì 1:10.

Ǹjẹ́ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lè dópin?

‘Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́, òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀.’—Aísáyà 2:2.

OHUN TÁWỌN KAN RÒ

Ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó ṣì ń bá a nìṣó títí di àkókò yìí ti mú káwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa kọminú pé bóyá la tiẹ̀ ti rí nǹkan ṣe sí ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Àwọn kan tiẹ̀ ti gba kámú pé kò lè ṣẹlẹ̀ láé pé kí gbogbo èèyàn gbà pé ẹ̀yà kan ò dára ju òmíràn lọ.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run ò ní gbà kí ìkórìíra tó wà láàárín àwọn ẹ̀yà máa bá a nìṣó títí ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, tọkùnrin tobìnrin “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” á máa sin Ọlọ́run níṣọ̀kan, wọ́n á sì máa fi ìfẹ́ tòótọ́ bá ara wọn lò. (Ìṣípayá 7:9) Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé kí Ọlọ́run gba àkóso nínú ọkàn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìjọba gidi kan tó máa mú àwọn àyípadà rere wá sí ayé yìí, ìyẹn ibi tí Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa gbé láìsí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. a

a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo orí kẹta nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.