Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ LÈ JÍǸDE?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?

“Ibi mẹ́ta ni mo rò pé èèyàn lè lọ lẹ́yìn tó bá kú, nínú kó lọ sí ọ̀run tàbí ọ̀run àpáàdì tàbí kó lọ sí pọ́gátórì. Mi ò rò pé ìwà mi dáa tó kí n rí ọ̀run wọ̀, àmọ́ kò burú débi tí máa fi lọ sí ọ̀run àpáàdì. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní pọ́gátórì kò sì yé mi rárá. Ẹnu àwọn èèyàn ni mo kúkú ti gbọ́ ọ, kò sí èyí tí mo rí nínú Bíbélì níbẹ̀.”—Lionel.

“Ohun tí wọ́n kọ́ mi ni pé, ọ̀run ni gbogbo èèyàn ń lọ lẹ́yìn ikú, àmọ́ mi ò gbà gbọ́. Ohun témi rò ni pé ikú lòpin ohun gbogbo, kò sì sí ìrètí kankan fáwọn tó ti kú.”—Fernando.

Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé: ‘Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú? Ṣé àwọn èèyàn wa tó ti kú ń jìyà níbì kan? Ṣé a tún lè pa dà rí wọn? Kí ló máa jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè rí wọn?’ Ó máa dáa ká mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì fi ikú wé. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ìrètí tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó wà fún àwọn tó ti kú.

Ipò wo làwọn òkú wà?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn. Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [tàbí Sàréè], ibi tí ìwọ ń lọ.” *Oníwàásù 9:5, 10.

Ṣìọ́ọ̀lù ìyẹn Sàréè ni ibi tí gbogbo èèyàn ń lọ lẹ́yìn ikú; ó sì ń ṣàpẹẹrẹ ipò tí èèyàn kò ti mọ nǹkan kan mọ́, téèyàn ò sì lè ṣe ohunkóhun. Kí ni ohun tí Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà rò nípa Ṣìọ́ọ̀lù? Ọjọ́ kan ṣoṣo ni Jóòbù pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, ni eéwo bá tún so sí gbogbo ara rẹ̀ látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Ó wá bẹ Ọlọ́run pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù [“ní ọ̀run àpáàdì,” Bíbélì Catholic Douay Version], pé ìwọ yóò pa mí mọ́.” (Jóòbù 1:13-19; 2:7; 14:13) Ó dájú pé Jóòbù kò gbà pé Ṣìọ́ọ̀lù ìyẹn Sàréè jẹ́ ibi tí èèyàn ti ń joró nínú iná, níbi tí ìyà rẹ̀ ti máa pọ̀ sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà pé ibẹ̀ ni òun ti máa rí ìtura.

Ọ̀nà míì wà tá a tún lè gbà mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú. A lè ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn mẹ́jọ tí wọ́n jíǹde.—Wo àpótí náà “ Àjíǹde Mẹ́jọ Tí Bíbélì Mẹ́nu Kàn.”

Kò sí ọ̀kan nínú àwọn mẹ́jọ yìí tó sọ bóyá òun lọ gbádùn tàbí pé òun joró nígbà tí òun kú. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wọ́n á sọ bí ọ̀hún ṣe rí fún àwọn míì. Tí wọ́n bá sì sọ ọ́, ǹjẹ́ irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní sí nínú Bíbélì fún wa? Àmọ́, kò sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ kò sọ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn kò mọ nǹkan kan nígbà tí wọ́n kú, àfi bí ẹni tó sun oorun àsùnwọra. Kódà, Bíbélì sábà máa ń fi ikú wé oorun. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Dáfídì àti Sítéfánù “sùn nínú ikú.”Ìṣe 7:60; 13:36.

Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fún àwọn tó ti kú? Ṣé wọ́n lè jí lójú oorun yìí?

^ ìpínrọ̀ 7 Ọ̀rọ̀ Hébérù náà “Ṣìọ́ọ̀lù” àti ti Gíríìkì náà “Hédíìsì” túmọ̀ sí “Sàréè.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì pè é ní “ọ̀run àpáàdì,” àmọ́ ẹ̀kọ́ pé èèyàn máa ń joró nínú ọ̀run àpáàdì kò bá Bíbélì mu.