Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Fara Da Àjálù Tí Ojú Ọjọ́ Máa Ń Fà?

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Fara Da Àjálù Tí Ojú Ọjọ́ Máa Ń Fà?

 Ṣé o wà lára ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó ń kojú ìṣòro ojú ọjọ́ tí kò dáa? Onírúurú ọ̀nà ni ojú ọjọ́ ń gbà yí pa dà, ìpalára tó ń ṣe sì pọ̀ gan-an. Ìjì líle, ìjì òjò àti ìjì àfẹ́yíká sábà máa ń fa ìrugùdù omi, omíyalé tàbí kó mú kí afẹ́fẹ́ ba àyíká jẹ́. Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá lè mú kí ilẹ̀ ya, ìjì sì lè mú kí mànàmáná sán ààrá tó lè fa iná ńlá tó máa délé dóko. Ọ̀dá, ìgbì ooru gbígbóná àti ìjì òjò náà sì máa ń ba nǹkan jẹ́ rẹ́kẹrẹ̀kẹ.

 Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, àjálù tó ń ba ilé àti ọ̀nà jẹ́ ń yára pọ̀ sí i ó sì ń burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àjọ kan tó ń jẹ́ International Federation of Red Cross and Red Crescent Societies sọ pé: “Iye àwọn tí àjálù ń ṣèpalára fún túbọ̀ ń pọ̀ sí i torí pé omíyalé, ìjì àti pàápàá jù lọ ọ̀gbẹlẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ èèyàn ń kú, àwọn míì ò lè gbọ́ bùkátà ara wọn, ilé ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń wó lọ́dọọdún.”

 Àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn lára, ó sì tún ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Inú wọn máa ń bà jẹ́ torí pé wọ́n pàdánù àwọn ohun ìní wọn, ilé wọn, tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé èèyàn wọn kan bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

 Tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí ọ̀rọ̀ ìtùnú tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ nínú Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn wàá tún rí ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn tírú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. (Róòmù 15:4) Bíbélì tún dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè, ìyẹn Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí irú nǹkan báyìí ṣẹlẹ̀, ṣé ó ń fìyà jẹ mí ni?

Ọlọ́run kọ́ ló ń fi àwọn àjálù tí ojú ọjọ́ ń fà jẹ àwọn èèyàn níyà

 Bíbélì fi kọ́ni pé Ọlọ́run kọ́ ló fà á táwọn èèyàn fi ń jìyà. Ó jẹ́ kó dá wa lójú pé “a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jémíìsì 1:13) Ìyẹn fi hàn pé òun kọ́ ló ń fa àwọn àjálù tí ojú ọjọ́ ń fà lónìí.

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìgbà kan wà tí Ọlọ́run lo omi àti àwọn nǹkan míì láti fìyà jẹ àwọn èèyàn búburú. Ìyẹn yàtọ̀ sí àwọn àjálù tó ń ba ilé àti ọ̀nà jẹ́, tó máa ń ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ tó sì máa ń pa ẹni rere àti ẹni búburú lára. Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn tó bá ṣe ohun tó tọ́, ó kọ́kọ́ máa ń kìlọ̀ fún wọn, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi fẹ́ ṣe ohun tó sọ. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ́ kí Ìkún Omi ọjọ́ Nóà ṣẹlẹ̀, ó kọ́kọ́ kìlọ̀ fáwọn èèyàn kí òjò tó rọ̀, ó sì dáàbò bo Nóà àti ìdílé rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 6:13; 2 Pétérù 2:5.

 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fi àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní jẹ àwọn èèyàn níyà, wo àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?

Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí torí ojú ọjọ́ tí kò dáa

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà a Ọlọ́run ó sì máa ń gba tẹni rò. Ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ń tuni nínú yìí.

  •   Àìsáyà 63:9: “Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá [Ọlọ́run] náà.”

     Ìtumọ̀: Ó máa ń dun Jèhófà gan-an táwọn èèyàn bá ń jìyà

  •   1 Pétérù 5:7: “Ó ń bójú tó yín.”

     Ìtumọ̀: Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ Jèhófà lógún.

 Torí pé Jèhófà bìkítà, àánú tó ní sí wa ń mú kó ràn wá lọ́wọ́. Ó ń tù wá nínú nípasẹ̀ ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì àti ìrètí tó ṣeé gbára lé pé lọ́jọ́ iwájú àjálù tí ojú ọjọ́ tí kò dáa ń fà ò ní sí mọ́.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Ìgbà tí kò ní sí ìṣòro ojú ọjọ́ tí kò dáa mọ́

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ‘fún wa ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’ (Jeremáyà 29:11) Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa bẹ̀rù ojú ọjọ́, ohun tó fẹ́ ni pé káwọn èèyàn máa gbádùn nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15; Àìsáyà 32:18.

 Ọlọ́run máa fi Ìjọba rẹ̀ tún ayé ṣe, Jésù ló sì máa jẹ́ Ọba Ìjọba náà. (Mátíù 6:10) Jésù ní ọgbọ́n àti agbára láti fòpin sí àjálù tí ojú ọjọ́ ń fà. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun lágbára lórí ojú ọjọ́. (Máàkù 4:37-41) Ó máa fi ọgbọ́n àti òye ṣàkóso, ó sì máa kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n á ṣe máa bójú tó àyíká wọn lọ́nà tí kò fi ní bà jẹ́. (Àìsáyà 11:2) Tí ìṣàkóso Jésù bá nasẹ̀ dé ayé, àjálù tí ojú ọjọ́ ń fà ò ní sí mọ́.

 Àmọ́ o lè ronú pé, ‘Ìgbà wo ni Jésù máa lo agbára rẹ̀ láti fòpin sí àjálù tí ojú ọjọ́ ń fà?’ Kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, wo àpilẹ̀kọọ̀ náà, “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

Ohun tá a lè ṣe tí àjálù tí ojú ọjọ́ ń fà bá ṣẹlẹ̀

 Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó o máa ṣe kí àjálù tí ojú ọjọ́ máa ń fà tó ṣẹlẹ̀, tó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ àti lẹ́yìn tó bá ṣẹlẹ̀.

  •   Kó tó ṣẹlẹ̀: Múra sílẹ̀ kó o lè tètè gbéra.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́, àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.”—Òwe 22:3.

     Ìtumọ̀: Mọ àwọn àjálù tó lè ṣẹlẹ̀ ládùúgbò rẹ, kó o lè mọ ohun tó o máa tètè ṣe láti dáàbò bo ìdílé rẹ.

     Ìrírí: “Lọ́jọ́ tí iná ńlá tó délé dóko sọ ládùúgbò wa, a ti múra sílẹ̀. Báàgì pàjáwìrì wa ti wà ní sẹpẹ́. Oògùn wà nínú ẹ̀, aṣọ náà sì wà nínú ẹ̀. Àwọn èèyàn ń sá sókè sódò níbi tá a wà, wọn ò mọ ohun tí wọ́n á ṣe. Ṣùgbọ́n a ní gbogbo ohun tá a nílò, ìyẹn dùn mọ́ mi nínú!”—Tamara, California, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

  •   Tó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́: Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni kó o gbájú mọ́.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.”—Lúùkù 12:15.

     Ìtumọ̀: Ẹ̀mí ṣe pàtàkì ju ohun ìní lọ.

     Ìrírí: “Nígbà tí Ìjì Líle Lawin b ba ilé wa jẹ́, mi ò mọ ohun tí mo máa ṣe. Torí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run látọkàn wá. Mo mọ̀ pé àwọn nǹkan tara la pàdánù, àmọ́ ẹ̀mí wa ò lọ sí i.”—Leslie, Philippines.

  •   Lẹ́yìn tó bá ṣẹlẹ̀: Má ṣàníyàn nípa ọ̀la.

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀.”—Mátíù 6:34.

     Ìtumọ̀: Má ṣe máa da ara ẹ láàmú jù nípa ohun tí ò tíì ṣẹlẹ̀.

     Ìrírí: “Lẹ́yìn tí Ìjì Irma jà tí omi sì ya wọ ilé mi, ọ̀pọ̀ ìpinnu ni mo ní láti ṣe ìyẹn sì jẹ́ kí gbogbo nǹkan tojú sú mi. Mo gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká má ṣàníyàn. Mo rí i pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti fara da ohun tó ju agbára mi lọ.”—Sally, Florida, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni tó lè túbọ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́, wo àpilẹ̀kọ náà, “Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là.”

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

b Wọ́n tún ń pè é ní Ìjì Líle Haima.