Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìṣòro Owó Tàbí Ti Mo Bá Jẹ Gbèsè?

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìṣòro Owó Tàbí Ti Mo Bá Jẹ Gbèsè?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn ìlànà Bíbélì mẹ́rin yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ní ìṣòro owó tàbí tó o bá jẹ gbèsè:

  1.   Wéwèé bí o ṣe máa náwó. “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Má ṣe máa kánjú ra nǹkan torí pé o rí i lórí igbá. Ní ètò ìnáwó, kó o sì máa tẹ̀ lé e.

  2.   Má tọrùn bọ gbèsè. “Ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí ó jẹ ní gbèsè.” (Òwe 22:7, Bíbélì Mímọ́) Tí o bá jẹ gbèsè tó ò sì lè máa san-án pa dà bó o ṣe sọ, lọ bá ẹni tó o jẹ lówó sọ̀rọ̀, kó o lè tún àdéhùn bí wàá ṣe máa dá owó náà pa dà ṣe. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún ẹni tó lọ fìwà òmùgọ̀ ṣe onídùúró fún ẹni tó yáwó, tó sì wá jẹ́ pé òun ló pa dà san gbèsè náà. Bíbélì sọ pé: “Rẹ ara rẹ sílẹ̀, kí o sì bẹ ọmọnìkejì rẹ ní ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dabọ̀. Má fi oorun kankan fún ojú rẹ, tàbí ìtòògbé kankan fún ojú rẹ.” (Òwe 6:1-5) Tí ẹni tó o jẹ ní gbèsè kò bá kọ́kọ́ dá ọ lóhùn, ìwọ ṣáà máa bẹ́ẹ̀ pé kó jẹ́ kó o ṣe àtúnṣe sí bí wàá ṣe máa dá owó tó o jẹ ẹ́ pa dà.

  3.   Ẹ fi owó sí àyè tó yẹ ẹ́. “Ẹni tí ó kánjú àtilà, ó ní ojú ìlara, kò sì rò pé òṣì n bọ̀ wá ta òun.” (Òwe 28:22, Bíbélì Mímọ́) Ìlara àti ìwọra lè mú kéèyàn jẹ gbèsè, ó sì lè gba àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run lọ́wọ́ èèyàn.

  4.   Ní ìtẹ́lọ́rùn. “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:8) Ti pé èèyàn ní owó kò sọ pé kó ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Àwọn tó láyọ̀ jù láyé yìí kò lówó rẹpẹtẹ. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run.​—Òwe 15:17; 1 Pétérù 5:6, 7.