Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arábìnrin Danusha Santhakumar (lápá òsì), tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ń fi àwòrán han ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arákùnrin àti Arábìnrin Modaragamage (lápá ọ̀tún), tó jẹ́ tọkọtaya tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Siri Láńkà ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan tó jẹ́ adití látorí íńtánẹ́ẹ̀tì

MAY 6, 2020
SRI LANKA

Àwọn Akéde Tó Ń Sọ Èdè Adití Kọ́ Àwọn Èèyàn Nípa Jèhófà Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Wọn Ò Lè Jáde Nílé

Àwọn Akéde Tó Ń Sọ Èdè Adití Kọ́ Àwọn Èèyàn Nípa Jèhófà Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Wọn Ò Lè Jáde Nílé

Bó ṣe wà láwọn orílẹ̀-èdè míì, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Siri Láńkà ṣòfin fún gbogbo àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n lè dènà títan àrùn corona kálẹ̀. Kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà ní àwùjọ tó ń sọ èdè adití lè pa òfin ìjọba mọ́, ẹ̀rọ ìgbàlódé ni wọ́n fi ń wàásù fún àwọn adití àtàwọn tó nira fún láti gbọ́rọ̀.

Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Vihanga Fernando máa ń fi lẹ́tà wàásù, àmọ́ torí pé kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ àwọn adití láti ka ọ̀rọ̀ tó wà lórí ìwé, arábìnrin yìí máa ń lo àwòrán nínú lẹ́tà rẹ̀ kó lè fi ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì.

Arábìnrin Fernando fí èdè Sinhala kọ lẹ́tà, ó sì tún lo àwòrán nínú lẹ́tà náà láti ṣàlàyé pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run

Arábìnrin Rosie Chithravelautham ò kọ́kọ́ gbà pé òun lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látorí íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó sọ pé: “Tí mo bá pe àwọn adití tẹ́lẹ̀, wọn kì í lóye ohun tí mò ń fọwọ́ sọ, torí fídíò náà máa ń ṣe ségesège.” Àmọ́, Arábìnrin Rosie pinnu pé òun ò ní dáwọ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dúró lákòókò àrùn corona yìí. Ó pinnu pé òun máa gbìyànjú fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì lẹ́ẹ̀kan sí i. Látìgbà yẹn sì rèé, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ta ló ń darí. Àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń gbádùn ìpàdé látorí íńtánẹ́ẹ̀tì.

March 2020 ni Arábìnrin Nirosha Shiranthi tó jẹ́ adití ṣèrìbọmi, ẹ̀rù sì máa ń bà á láti wàásù fáwọn èèyàn látorí íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kóun lè borí ìṣòro yìí, lẹ́yìn náà, ó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ adití ló gba ìkésíni tí Nirosha fi ránṣẹ́ sí wọn pé kí wọ́n wo fídíò Ìrántí Ikú Kristi, púpọ̀ nínú wọn ló sì fẹ́ mọ̀ nípa àmì ọjọ́ ìkẹyìn. Ní báyìí, àwọn méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Nirosha ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ní: “Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá ń wàásù. Bá ò tiẹ̀ lè kúrò nílé, ìyẹn ò ní ká má wàásù. Jèhófà máa ń mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.” Nirosha ti pinnu pé òun á máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nìṣó.

Àwọn ìrírí tá a gbọ́ láti orílẹ̀-èdè Siri Láńkà múnú wa dùn gan-an. Ohun tó sì mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé, àwọn ará wa tó jẹ́ adití, àtàwọn tó nira fún láti gbọ́rọ̀ ń sapá láti máa ṣe ohun tó ń mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà.—Sáàmù 113:1.