Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé

Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé

Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé

Kí Ni Kò Sí Nínú Àwòrán Yìí?

Ka Àwọn Onídàájọ́ 7:​15-​22. Kó o sì wo àwòrán yìí. Àwọn nǹkan wo ni kò sí nínú àwòrán náà? Kọ ìdáhùn rẹ sórí àwọn ìlà yìí.

1. ․․․․․

2. ․․․․․

3. ․․․․․

FÚN ÌJÍRÒRÒ:

Kí ló jẹ́ kí Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣẹ́gun? Kí ló jẹ́ kí Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ nígboyà? Àwọn ìgbà wo ni ìwọ náà nílò ìgboyà bíi ti Gídíónì?

KÍ LO MỌ̀ NÍPA DÁFÍDÌ ỌBA?

4. Ẹ̀gbọ́n ọkùnrin mélòó ni Dáfídì ní?

AMỌ̀NÀ: Ka 1 Sámúẹ́lì 16:​10, 11.

․․․․․

5. Kí ni orúkọ arákùnrin Dáfídì tó dàgbà jù lọ?

AMỌ̀NÀ: Ká 1 Sámúẹ́lì 17:⁠28.

․․․․․

FÚN ÌJÍRÒRÒ:

Kí lo rò pé ó mú kí ẹ̀gbọ́n Dáfídì tó dàgbà jù lọ bínú sí Dáfídì? Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa fi inúure hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ?

NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ

Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.

OJÚ ÌWÉ 4 Irú ìdè wo ni ìgbéyàwó jẹ́? Mátíù 19:․․․

OJÚ ÌWÉ 9 ‘Ẹwà ni ó jẹ́’ láti ṣe kí ni? Òwe 19:․․․

OJÚ ÌWÉ 10 Ọlọ́run ti dá ọjọ́ kan láti ṣe kí ni? Ìṣe 17:․․․

OJÚ ÌWÉ 12 Kí ló ṣe àdàkàdekè? Jeremáyà 17:․․․

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ

1. Ìwo.

2. Ìṣà.

3. Ògùṣọ̀.

4. Méje.

5. Élíábù.