Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Má Fi Ìfẹ́sọ́nà Ṣeré

Ẹ Má Fi Ìfẹ́sọ́nà Ṣeré

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ẹ Má Fi Ìfẹ́sọ́nà Ṣeré

Julie àti Lee ń fẹ́ra wọn, wọ́n sì ti pinnu pé àwọn ò ní ṣèṣekúṣe. a Àmọ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbà táwọn méjèèjì dá wà, ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ìbálòpọ̀. Àmọ́, wọ́n pe orí ara wọn wálé kó tó pẹ́ jù, wọn ò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì.

Ẹ̀SÌN tòótọ́ kọjá kéèyàn wulẹ̀ máa lọ sílé ìjọsìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tó máa ń nípa lórí ìṣe àtàwọn ìlànà téèyàn fi ń ṣèwà hù. Jésù Kristi sọ pé àwọn tó bá ń “ṣe ìfẹ́” Ọlọ́run nìkan ló máa rí ojú rere Ọlọ́run. (Mátíù 7:21) Tá a bá fẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sí wa, a gbọ́dọ̀ máa fọ̀wọ̀ wọ ẹni tá à ń fẹ́, ká má sì fi ọ̀rọ̀ ìfẹ́sọ́nà ṣeré.

Báwo ni ìwọ àti ẹni tó ò ń fẹ́ ṣe lè mú kí àjọṣe yín jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run láìka bí ìṣekúṣe tó kún inú ayé ṣe ń mú kó ṣòro fáwọn tó ń fẹ́ra wọn láti wà láìní ìbálòpọ̀? Ohun àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ni pé àǹfààní wa ni àwọn ìlànà Ọlọ́run wà fún. Èkejì ni pé ẹ gbọ́dọ̀ gbà pé ó rọrùn fáwa èèyàn láti ṣohun tí kò tọ́ torí pé a jẹ́ aláìpé. Ẹ̀kẹta ni pé kẹ́ ẹ jọ pinnu ọ̀nà tó tọ́ láti gbà fi ìfẹ́ hàn. Ẹ̀kẹrin sì ni pé kẹ́ ẹ fi Ọlọ́run ṣe ẹnì kẹta yín. Jẹ́ ká gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

Àwọn Ìlànà Tó Wà fún Àǹfààní Wa

Ìwé Aísáyà 48:17, 18, kà pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”

Bẹ́ẹ̀ ni, àǹfààní wa làwọn àṣẹ àtàwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì Mímọ́, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí wà fún. (2 Tímótì 3:16, 17) Àwọn ìlànà yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa bìkítà nípa wa, ó fẹ́ ká láyọ̀, ó sì fẹ́ ká ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé wa. (Sáàmù 19:7-10) Ṣé bó ṣe rí lọ́kàn rẹ nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe lèyí fi hàn pé o ní ọgbọ́n tòótọ́.

Gbà Pé Ó Rọrùn Láti Ṣohun Tí Kò Tọ́

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣe máa ń ṣe, Jèhófà máa ń sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ fún wa, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ó rọrùn fáwa èèyàn láti ṣohun tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó kìlọ̀ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Bíbélì tún sọ pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.”—Òwe 28:26.

Báwo làwọn tó ń fẹ́ra wọn ṣe lè fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà àwọn? Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń wà láwọn ibi tó ti máa rọrùn fún wọn láti sún mọ́ ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ, bíi tàwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Wọ́n tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń kọ etí ikún sáwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ń fún wọn. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀, pàápàá jù lọ nígbà èwe, máa ń dà bí ẹ̀rọ alágbára tó nílò àbójútó àrà-ọ̀tọ̀.

Torí náà, àwọn ọ̀dọ́, tí wọ́n ‘ń rìn nínú ọgbọ́n Ọlọ́run’ máa ń fọwọ́ pàtàkì mú ìtọ́sọ́nà àwọn òbí. Wọ́n máa ń fetí sí ìmọ̀ràn àwọn òbí wọn, torí wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ táwọn òbí wọn ní sí wọn ló mú kí wọ́n máa bá wọn wí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà lè bí àwọn ọmọ náà nínú. Ká sòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run, Bàbá rẹ ọ̀run ló fẹ́ràn rẹ jù lọ, òun ló gbà ẹ́ nímọ̀ràn pé kó o “mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn-àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara rẹ.” (Oníwàásù 11:9, 10) Báwo lo ṣe lè bẹ́ẹ̀? Nípa yíyẹra fún èrò tí kò tọ́.

Ẹ Jọ Pinnu Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Gbà Fi Ìfẹ́ Hàn

“Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” (Òwe 13:10) Ní gbàrà tí ọkùnrin àti obìnrin tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n bá ti ń fẹ́ra ni wọ́n ti máa ń fi ọ̀rọ̀ yìí sílò, wọ́n jọ máa pinnu àwọn ọ̀nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n lè máa gbà fìfẹ́ hàn sí ara wọn, wọ́n sì máa ń rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn. Bí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn láwọn ọ̀nà tí kò tọ́ tàbí tí wọ́n dára wọn lójú ju bó ṣe yẹ lọ, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń wakọ̀ níwàkuwà. Lẹ́yìn téèyàn bá ti fara pa nínú jàǹbá ọkọ̀ kọ́ ló yẹ kó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pinnu ohun tóun máa ṣe láti yẹra fún jàǹbá náà!

Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Owe 22:3) Àwọn tó ń fẹ́ra wọn lè yẹra fún wàhálà bí wọ́n bá jọ ń wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tó níwà ọmọlúwàbí tàbí kí wọ́n rí i dájú pé àwọn kì í dá wà. Téèyàn bá hùwà òmùgọ̀ nígbà ìfẹ́sọ́nà, ó lè ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn onítọ̀hún, ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ò ní fi ọ̀wọ̀ tó yẹ wọ ara yín mọ́, ó sì lè kó ìtìjú bá gbogbo àwọn tọ́ràn náà bá kàn, tó fi mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí. Torí náà, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n; ẹ jọ pinnu láti máa fàwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ ṣèwà hù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ohunkóhun yẹ ìpinnu yín!

Ẹ Fi Jèhófà Ṣe ‘Fọ́nrán Kẹta’

Ìgbéyàwó dà bí okùn onífọ́nrán mẹ́ta, nínú èyí tí Ọlọ́run ti ṣàpẹẹrẹ fọ́nrán tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ìwé Oníwàásù 4:12 sọ pé: “Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò . . . lè tètè fà já sí méjì.” Ìlànà yìí ṣeé lò fáwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Àwọn tó bá fẹ́ kí Ọlọ́run bù kún àjọṣe àwọn máa rí ìbùkún yẹn gbà bí àwọn méjèèjì bá sún mọ́ Ọlọ́run lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Sáàmù 1:1-3 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú . . . Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru . . . , gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”

Tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí tòótọ́ nígbèésí ayé wa, títí kan àṣeyọrí nínú ọ̀rọ̀ ìfẹ́sọ́nà àti ìgbéyàwó, ó di dandan ká ṣàwọn nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Ó ṣe tán, òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ẹ̀bùn àtàtà látọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ìfẹ́ àárín takọtabo àti ìgbéyàwó jẹ́. Torí náà, ó yẹ ká fi hàn pé a mọyì àwọn ẹ̀bùn yìí gidigidi.—Jákọ́bù 1:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ ohun rere fún wa?—Aísáyà 48:17, 18.

● Òtítọ́ wo ló yẹ ká mọ̀ nípa ara wa?—Jeremáyà 17:9.

● Báwo ni ọkùnrin àti obìnrin ṣe lè ṣàṣeyọrí nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà àti lẹ́yìn ìgbéyàwó?—Sáàmù 1:1-3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ní gbàrà tí ọkùnrin àti obìnrin tó jẹ ọlọ́gbọ́n bá ti ń fẹ́ra wọn ni wọ́n ti jọ máa pinnu àwọn ọ̀nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n lè gbà máa fìfẹ́ hàn síra wọn, wọ́n sì máa ń rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn