Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Burú Láti Fẹ́ Dá Wà?

Ṣé Ó Burú Láti Fẹ́ Dá Wà?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Ṣé Ó Burú Láti Fẹ́ Dá Wà?

Fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó o rò pé wàá ṣe tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí bá ṣẹlẹ̀.

1. O wà nínú yàrá rẹ, ó sì ti ilẹ̀kùn, àmọ́ ńṣe ni àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n rẹ wọlé lójijì láì kanlẹ̀kùn.

‘Kò síṣòro . . . Bí èmi náà ṣe máa ń wọ yàrá wọn làìkan ilẹ̀kùn nìyẹn.’

‘Irú kí nìyẹn! Bó bá jẹ́ pé mò ń múra lọ́wọ́ ńkọ́?’

2. Ò ń bá ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ lórí fóònù, mọ́mì ẹ wà níbi tí wọ́n ti lè gbọ́ yín, ó sì dájú pé gbogbo ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ ni wọ́n ń tẹ́tí sí.

‘Kò síṣòro . . . Mi ò lọ́rọ̀ àṣírí kankan.’

‘Ìyẹn ò dáa rárá! Ńṣe ló máa dà bíi pé wọ́n ń ṣọ́ mi lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀!’

3. Bó o ṣe ń wọlé làwọn òbí ẹ bẹ̀rẹ̀ sí da ìbéèrè bò ẹ́. “Ibo lo lọ? Kí lo ṣe lọ́hùn-ún? Àwọn wo lẹ jọ lọ?”

‘Kò síṣòro . . . Bí wọn ò tiẹ̀ béèrè gan-an, màá sọ fún wọn.’

‘Ó máa sú mi! Á jẹ́ pé àwọn òbí mi ò fọkàn tán mi nìyẹn!’

NÍGBÀ tó o wà lọ́mọdé, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ dídáwà má ṣe pàtàkì sí ẹ. Báwọn àbúrò ẹ bá já wọ yàrá ẹ, ṣe ni wàá bá wọn ṣeré. Táwọn òbí ẹ bá bi ẹ́ ní ìbéèrè, o kì í rò ó lẹ́ẹ̀mejì kó o tó dá wọn lóhùn. Nígbà yẹn o ò fi ohunkóhun pa mọ́ nípa ara rẹ. Àmọ́ nǹkan ti yí pa dà báyìí, nígbà míì o kì í fẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó ò ń ṣe. Corey tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] sọ pé: “Ó máa ń wù mí pé kí n dá àwọn nǹkan kan ṣe láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni mọ̀ sí i.” a

Kí ló fà á tó o fi wá dẹni tó ń fẹ́ láti máa dá wà báyìí? Ọ̀kan lára ohun tó fà á ni pé o ti ń dàgbà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara rẹ bó o ṣe ń bàlágà lè jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí pàfiyèsí sí ara rẹ, ojú tiẹ̀ lè máa tì ẹ́ nílé pàápàá. Bákan náà, bó o ṣe ń dàgbà sí i, á túbọ̀ máa wù ẹ́ láti dá ronú lórí àwọn nǹkan kan. Èyí jẹ́ àmì pé o ti ń ní “agbára láti ronú,” ànímọ́ tí Bíbélì sì sọ pé ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ ní nìyẹn. (Òwe 1:1, 4; Diutarónómì 32:29) Nígbà tí Jésù alára fẹ́ ronú jinlẹ̀, ó lọ sí “ibi tí ó dá.”—Mátíù 14:13.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé abẹ́ àwọn òbí rẹ lo ṣì wà, wọ́n ṣì lẹ́tọ̀ọ́ láti máa mọ ohun tó ò ń ṣe. (Éfésù 6:1) Àmọ́, ìṣòro lè yọjú bó o ṣe ń dàgbà tó o sì fẹ́ máa dá nǹkan ṣe, táwọn náà sì ń fẹ́ mọ ohun tó ò ń ṣe. Báwo lo ṣe lè bójú tó ọ̀ràn náà? Jẹ́ ká wo ohun méjì tó lè fa ìṣòro.

Tó O Bá Fẹ́ Dá Nìkan Wà

Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì ló lè mú kó o fẹ́ dá nìkan wà. Ó lè jẹ́ pé o kàn fẹ́ “sinmi díẹ̀” ni. (Máàkù 6:31) Ó sì lè jẹ́ pé tó o bá fẹ́ gbàdúrà, o fẹ́ ṣe ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó ní: “Lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ.” (Mátíù 6:6; Máàkù 1:35) Ibi tí ìṣòro wà ni pé, tó o bá ti ilẹ̀kùn yàrá (ìyẹn tó o bá ní yàrá tìẹ), àwọn òbí ẹ lè má mọ̀ pé ńṣe lò ń gbàdúrà. Àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ sì lè má mọ̀ pé ńṣe lo fẹ́ dá wà.

Ohun tó o lè ṣe. Kàkà tó o máa fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí fa awuyewuye, ṣe ohun tó tẹ̀ lé e yìí.

● Láti yanjú ìṣòro tó lè wáyé láàárín ìwọ àtàwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹ, o lè ṣe àwọn òfin kan tí kò le, tó máa jẹ́ kó o lè ráyè dá nìkan wà. Tó bá pọn dandan, o lè ní káwọn òbí rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

● Gbìyànjú láti lóye èrò àwọn òbí rẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Rebekah tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń yọjú wò mí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Èmi náà sì mọ̀ lóòótọ́ pé bí mo bá bímọ, bí èmi náà á ṣe máa ṣe nìyẹn, pàápàá tórí ìdẹwò tó ń kojú àwọn ọ̀dọ́ lónìí!” Bíi ti Rebekah, ǹjẹ́ ìwọ náà lè ro ohun tó fà á táwọn òbí ẹ fi fẹ́ mọ ohun tó ò ń ṣe?—Òwe 19:11.

● Pẹ̀lú òótọ́ inú, bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo ti ṣe ohun kan tó máa ń jẹ́ kí ara fu àwọn òbí mi pé ohun burúkú tí mo fẹ́ ṣe ló jẹ́ kí n ti ilẹ̀kùn mọ́rí? Ṣé kì í ṣe pé ńṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kí wọ́n tó lè mọ àwọn nǹkan nípa mi, torí mi kì í fẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí mò ń ṣe?’ Bó ṣe sábà máa ń rí, bó bá jẹ́ pé o kì í fi nǹkan pa mọ́ fáwọn òbí rẹ, wọn ò ní máa fura sí ẹ. b

Ohun tí màá ṣe. Kọ ohun tó o máa sọ fáwọn òbí rẹ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.

․․․․․

Tó O Bá Fẹ́ Yan Ọ̀rẹ́

Kò burú láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun bó o ṣe ń bàlágà. Bákan náà, kò burú báwọn òbí rẹ bá fẹ́ mọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn nǹkan tẹ́ ẹ jọ máa ń ṣe. Àwọn òbí ẹ mọ̀ pé ara ojúṣe wọn ló jẹ́ láti mọ àwọn tó ò ń bá rìn. Àmọ́ lójú tìẹ, ó lè dà bí i pé àwọn òbí ẹ ti tàṣejù bọ ọ̀rọ̀ yìí. Amy tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sọ pé: “Mo fẹ́ ní fóònù alágbèéká tèmi àti àdírẹ́sì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, mi ò sì fẹ́ káwọn òbí mi máa bi mí ní gbogbo ìgbà pé ta ni mò ń bá sọ̀rọ̀.”

Ohun tó o lè ṣe. Kí ọ̀rọ̀ yìí má bàa ba àjọṣe ìwọ àtàwọn òbí rẹ jẹ́, o lè ṣe ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí.

● Jẹ́ káwọn òbí rẹ mọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dáadáa, má fi wọ́n pa mọ́. Ó ṣe tán, o ò ní fẹ́ káwọn òbí rẹ máa fimú fínlẹ̀ láti mọ àwọn tó ò ń bá rìn, àmọ́ ohun tí wọ́n máa ṣe nìyẹn tó o bá ń fàwọn ọ̀rẹ́ rẹ pa mọ́. Rántí pé, àwọn òbí rẹ mọ ipa táwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè ní lórí rẹ. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Báwọn òbí rẹ bá ṣe mọ àwọn tó ò ń bá rìn tó, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wọn á ṣe balẹ̀ tó.

● Fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá àwọn òbí ẹ sọ ọ̀rọ̀ náà. Má fẹ̀sùn kàn wọ́n pé ọ̀rọ̀ tí kò kàn wọ́n ni wọ́n ń dá sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè sọ pé, “Ó dà bíi pé gbogbo nǹkan tí mo bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ lẹ máa ń fẹ́ mọ̀ tẹ́ ẹ sì máa ń bá mi wí lé lórí. Ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó ṣòro fún mi láti bá àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀.” Ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ túbọ̀ wá fún ìwọ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ láyè.—Òwe 16:23.

● Má tan ara rẹ jẹ: Ṣé o kàn fẹ́ dá nìkan wà ni, àbí ṣe lo fẹ́ máa ṣe àwọn nǹkan tí ẹlòmíì ò gbọ́dọ̀ gbọ́? Brittany tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún [22] sọ pé: “Bó o bá ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, tí wọ́n sì ń fẹ́ mọ ohun tó ò ń ṣe, ohun tó yẹ kó wá sí ẹ lọ́kàn ni pé: ‘Kò yẹ kí n fi nǹkan kan pa mọ́, torí mi ò ṣe ohun tó burú.’ Àmọ́ tó o bá ṣì fẹ́ máa fi àwọn nǹkan tó ò ń ṣe pa mọ́, á jẹ́ pé nǹkan míì wà níbẹ̀ nìyẹn.”

Ohun tí màá ṣe. Kọ ohun tó o máa sọ fáwọn òbí rẹ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.

․․․․․

Ohun Tó O Lè Ṣe

Ní báyìí, wá ronú nípa àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe láti yanjú ìṣòro yìí.

Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́: Mọ ohun tó lè fa ìṣòro.

Àwọn nǹkan wo lo rò pé o máa fẹ́ ṣe tó máa gba pé kó o dá nìkan wà?

․․․․․

Ìgbésẹ̀ Kejì: Ronú nípa ohun tó wà lọ́kàn àwọn òbí rẹ.

Kí lo rò pé ó fà á tí wọ́n fi fẹ́ mọ ohun tó ò ń ṣe?

․․․․․

Ìgbésẹ̀ Kẹta: Wá ojútùú.

(a) Ronú nípa, ó kéré tán, àṣìṣe kan tó o ti ṣe, tó ṣeé ṣe kó dá kún ìṣòro náà. Kọ ọ́ sórí ìlà yìí.

․․․․․

(b) Àwọn àtúnṣe wo lo lè ṣe láti yanjú ìṣòro tó o kọ yìí?

․․․․․

(d) Kí lo máa fẹ́ kí àwọn òbí rẹ ṣe láti yanjú ìṣòro yìí?

․․․․․

Ìgbésẹ̀ Kẹrin: Ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Wá àkókò tó wọ̀ láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o kọ yìí.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Tó o bá ń finú han àwọn òbí rẹ, síbẹ̀ tí wọn ò fọkàn tán ẹ, fara balẹ̀, kó o sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún wọn. Tẹ́tí sílẹ̀ dáádáá kó o lè mọ ohun tó ń kọ wọ́n lóminú, kí ìwọ náà sì rí i pé o ò ṣe ohunkóhun láti dá kún ìṣòro yẹn.—Jákọ́bù 1:19.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

● Kí nìdí táwọn òbí rẹ fi lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ ohun tó ò ń ṣe?

● Bó o bá sapá láti mọ bó ṣe yẹ kó o máa bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó o mọ bó o ṣe máa bá àwọn tó bá dàgbà jù ẹ́ lọ sọ̀rọ̀?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Tí àwọn ọ̀dọ́ ò bá fi ohun tí wọ́n ń ṣe pa mọ́, àwọn òbí ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá bí wọ́n à ṣe ka ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọ wọn fi ń ránṣẹ́ tàbí èyí tí wọ́n ń gbà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí fóònù, kí wọ́n tó mọ ohun táwọn ọmọ wọn ń ṣe.”

“Mi ò ní bínú táwọn òbí mi bá ka àwọn lẹ́tà tí mo ní lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Níwọ̀n bí àwọn agbanisíṣẹ́ ti lẹ́tọ̀ọ́ láti ka lẹ́tà táwọn òṣìṣẹ́ wọn ní lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kò burú táwọn òbí bá ka lẹ́tà táwọn ọmọ wọn ní lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”

“Àwọn òbí kò fẹ́ kí ohun tí kò dáa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn, ìdí nìyẹn tó fi máa ń dà bíi pé wọ́n tojú bọ ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn nígbà míì. Ó máa ń dà bíi pé kò yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bí èmi náà bá jẹ́ òbí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tí wọ́n ṣe yẹn lèmi náà máa ṣe.”

[Àwọn àwòrán]

Eden

Kevin

Alana

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

● Ọmọ rẹ ọkùnrin wà nínú yàrá, ó sì ti ilẹ̀kùn. Ṣó yẹ kó o kàn já wọlé láì kan ilẹ̀kùn?

● Nígbà tí ọmọ rẹ obìnrin ń kánjú lọ síléèwé, ó gbàgbé fóònù rẹ̀ sílé. Ṣó yẹ kó o ka àwọn lẹ́tà tó wà lórí fóònù rẹ̀?

Kò rọrùn láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Àmọ́, o lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ ohun tí ọmọ rẹ ń ṣe, ojúṣe rẹ sì ni láti dáàbò bò ó. Síbẹ̀, o ò lè máa fìgbà gbogbo ṣọ́ ọmọ rẹ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, kó o sì fẹ́ mọ gbogbo ohun tó ń ṣe. Kí lo wá lè ṣe tó ò fi ní tàṣejù bọ̀ ọ́?

Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kó yé ẹ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà táwọn ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà bá fẹ́ dá nìkan wà ló jẹ́ pé ohun tí ò dáa ni wọ́n fẹ́ ṣe. Báwọn ọmọ bá ti ń dàgbà wọ́n máa ń fẹ́ dá wà. Dídá wà máa jẹ́ káwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà mọ̀ bóyá àwọn ti lè dá nǹkan ṣe, á jẹ́ kí wọ́n lè yàn ọ̀rẹ́, kí wọ́n sì lè lo “agbára ìmọnúúrò” wọn láti yanjú àwọn ìṣòro wọn. (Róòmù 12:1, 2) Dídáwà tún máa ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ mọ béèyàn ṣe ń ronú, èyí sì ṣe pàtàkì tí wọ́n bá máa di ẹni tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún. (1 Kọ́ríńtì 13:11) Ó tún máa ń jẹ́ kí wọ́n lè lo làákàyè kí wọ́n tó fèsì àwọn ìbéèrè tó ṣòro dáhùn.—Òwe 15:28.

Ohun kejì tó yẹ kó o mọ̀ ni pé tó o bá fẹ́ máa pinnu gbogbo ohun tí ọmọ rẹ ń ṣe, inú ọmọ náà kò ní dùn, ìyẹn sì lè mú kó ya ìyàkuyà. (Éfésù 6:4; Kólósè 3:21) Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé kó o fi ọmọ náà sílẹ̀ kó máa ṣe bó ṣe wù ú? Rárá o, tórí ìwọ ṣì ni òbí rẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó yẹ kó jẹ ẹ́ lógún ni bí ọmọ rẹ ṣe máa ní ẹ̀rí ọkàn rere. (Diutarónómì 6:6, 7; Òwe 22:6) Wàá wá rí i pé ó sàn kó o máa tọ́ ọmọ rẹ sọ́nà ju kó o máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ lọ.

Ohun kẹta ni pé kí ìwọ àti ọmọ rẹ jíròrò ọ̀rọ̀ náà. Fetí sílẹ̀ bó ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Ṣé o lè fara mọ́ ohun tó bá sọ nígbà míì? (Fílípì 4:5) Sọ fún un pé wàá fún un lómìnira dé ìwọ̀n àyè kan, bí kò bá ti ní ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kó o fọkàn tán an. Jẹ́ kó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bó bá ṣe ohun tí kò yẹ, kó o sì dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Mọ̀ dájú pé o fún ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà lómìnira láti máa dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí èyí ò sì ní sọ ẹ́ di òbí tí kò mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Bó ṣe jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kó o tó gbowó, o gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan kan kí wọ́n tó lè fọkàn tán ẹ