Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Èké Kan Ló Ń Fa Òmíràn

Ẹ̀kọ́ Èké Kan Ló Ń Fa Òmíràn

Ẹ̀kọ́ Èké Kan Ló Ń Fa Òmíràn

ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà láyé nígbà tí ọ̀rúndún kìíní ń parí lọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra.” Kí ló fẹ́ kí wọ́n máa ṣọ́ra fún? Ó ní: “Bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.”—Kólósè 2:8.

Àwọn Kristẹni kan kò ka ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fún wọn ní ìdajì ọ̀rúndún kejì yìí sí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tó wà nígbà àtijọ́ gbà gbọ́ ṣàlàyé ìgbàgbọ́ tiwọn náà. Kí nìdí? Wọ́n fẹ́ kí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Ilẹ̀ Ọba Róòmù tẹ́wọ́ gbà wọ́n, kí àwọn sì lè tipa bẹ́ẹ̀ yí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn pa dà.

Justin Martyr jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tó gbajúmọ̀ jù lọ nínú àwọn Kristẹni yìí, ó gbà gbọ́ pé ẹni tó jẹ́ Agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run ti fi ara rẹ̀ han àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Gíríìsì tipẹ́tipẹ́ kí Jésù tó dé. Justin àti àwọn olùkọ́ míì tí wọ́n ń fi irú èrò yìí kọ́ àwọn èèyàn tún sọ pé, ipa tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti àwọn ìtàn àròsọ kó nínú ìsìn Kristẹni ló jẹ́ kí onírúurú èèyàn tẹ́wọ́ gba ìsìn náà.

Oríṣi ìsìn Kristẹni tí Justin Martyr dá sílẹ̀ ṣàṣeyọrí gidigidi nínú yíyí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn pa dà. Àmọ́ ṣá o, gbígbà tí wọ́n ń gba àwọn ẹ̀kọ́ èké kan láàyè ló ń fa òmíràn, àwọn ẹ̀kọ́ èké yìí ló sì wá di ohun tí àwọn èèyàn wá mọ̀ lónìí sí ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni. Láti mọ àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké yìí, jẹ́ ká fi àwọn ohun tí àwọn ìwé tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́ka sí yìí sọ wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì kọ́ni.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Ẹ̀ṣù: Barrators—Giampolo/The Doré Illustrations For Dante’s Divine Comedy/Dover Publications Inc.; àwọn áńgẹ́lì: Art Resource, NY; ère mẹ́talọ́kan: Museo Bardini, Florence