Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Èké Kẹfà: Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Lílo Ère Àti Àwòrán Nínú Ìjọsìn

Ẹ̀kọ́ Èké Kẹfà: Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Lílo Ère Àti Àwòrán Nínú Ìjọsìn

Ẹ̀kọ́ Èké Kẹfà: Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Lílo Ère Àti Àwòrán Nínú Ìjọsìn

Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? “Àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìsìn Kristẹni kì í lo èrè nínú ìjọsìn wọn . . . Ohun tó mú kí wọ́n fàyè gba lílo ère nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì láti ọ̀rúndún kẹrin sí ìkarùn ni pé, àwọn kan gbà pé bí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni bá ń rí ère, ó máa rọrùn fún wọn láti mọ àwọn òkodoro òtítọ́ kan nípa ìsìn Kristẹni ju kí wọ́n gbọ́ ìwàásù tàbí kí wọ́n ka àwọn ìwé lọ.”—Ìwé Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, látọwọ́ McClintock àti Strong, Ìdìpọ̀ 4, ojú ìwé 503 àti 504.

Kí ni Bíbélì sọ? ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ yá ère fún ara rẹ, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ lókè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n.’ (Ẹ́kísódù 20:4, 5, Bibeli Mimọ) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”—1 Jòhánù 5:21.

Ṣé ère ló máa jẹ́ ká lè sún mọ́ ẹni tí wọ́n gbẹ́ ère rẹ̀, táá sì jẹ́ ká bọ̀wọ̀ fún onítọ̀hùn gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti máa ń sọ? Ìwé The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé olórí ìdí tí wọ́n fi kọ́kọ́ ń lo ère ni láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ àti láti ṣe ẹ̀ṣọ́; ó ṣe tán ìdí tí wọ́n sọ pé àwọn fi ń lò ó nìyẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn rẹ̀. Òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro lọ̀rọ̀ yìí nípa àwọn àwòrán tó wá di apá pàtàkì nínú ìjọsìn àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn.” Àmọ́ ṣá o, wòlíì Aísáyà bi wá ní ìbéèrè tó tọ̀nà yìí pé: ‘Ta ni ẹ̀yin ó ha fi Ọlọ́run wé? Àbí àwòrán kí ni ẹ̀yin ó fi ṣé àkàwé rẹ̀?’—Aísáyà 40:18, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Aísáyà 44:13-19; Ìṣe 10:25, 26; 17:29; 2 Kọ́ríńtì 5:7

ÒKODORO ÒTÍTỌ́:

Ọlọ́run kò fọwọ́ sí lílo ère àti àwòrán nínú ìjọsìn

KỌ Ẹ̀KỌ́ ÈKÉ SÍLẸ̀ KÓ O SÌ KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Ibo la wá lè parí èrò sí látinú àwọn àyẹ̀wò ráńpẹ́ tá a ṣe nípa àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ṣì fi ń kọ́ni? Àwọn ‘ìtàn asán [ìyẹn myʹthos, lédè Gíríìkì]’ tí wọ́n fi ‘ọgbọ́n-kọ́gbọ́n là sílẹ̀’ yìí kò lè bá òtítọ́ tó rọrùn tó sì tuni nínú tó wà nínú Bíbélì dọ́gba láé.—2 Pétérù 1:16, Bibeli Mimọ.

Nítorí náà, má ṣe jáfara láti fi àwọn ohun tó o ti kọ́ wéra pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ orísun òtítọ́, kó o sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú òótọ́ ọkàn. (Jòhánù 17:17) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìlérí yìí á ṣẹ sí ẹ lára pé: ‘Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.’—Jòhánù 8:32, Bibeli Ajuwe.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.