Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Tó Gbàfiyèsí Nípa Bí Bíbélì Kò Ṣe Pa Run

Ìtàn Tó Gbàfiyèsí Nípa Bí Bíbélì Kò Ṣe Pa Run

Ìtàn Tó Gbàfiyèsí Nípa Bí Bíbélì Kò Ṣe Pa Run

BÍBÉLÌ ni ìwé tí àwọn èèyàn tíì ní lọ́wọ́ jù lọ, ó tó nǹkan bíi bílíọ̀nù márùn-ún ẹ̀dà tó ti wà lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Ní ọdún 2007 nìkan, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́ta àti ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [64,600,000] Bíbélì ni wọ́n tẹ̀ jáde. Èyí sì pọ̀ gan-an ju iye ẹ̀dà ìwé míì tó tà jù lọ lọ́dún náà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí ẹ̀dà tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ kò ju mílíọ̀nù méjìlá lọ.

Kó tó di pé Bíbélì di ìwé tí wọ́n tíì tẹ̀ síta jù lọ lágbàáyé, ọ̀pọ̀ ewu ló là kọjá. Ìtàn fi hàn pé, wọ́n fòfin de Bíbélì nígbà kan rí, wọ́n dáná sun ún, wọ́n fìyà jẹ àwọn tí wọ́n gbá mú pé wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí èdè míì, wọ́n sì pa wọ́n. Síbẹ̀, ọkàn lára ewu tó lágbára jù lọ tó dojú kọ Bíbélì kì í ṣe àtakò tí wọ́n ṣe sí í, bí kò ṣe bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́ díẹ̀díẹ̀. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rùn [66] ló para pọ̀ di Bíbélì, ó lé ní ẹgbẹ̀ta [3,000] ọdún sẹ́yìn tí àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ èyí tó pẹ́ jù lọ lára rẹ̀, tàbí kí wọ́n kó o jọ. Orí àwọn nǹkan tó lè bà jẹ́ bí òrépèté àti awọ ni àwọn tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí yìí àti àwọn tó ṣe àdàkọ rẹ̀ kọ wọ́n sí. Kò sí èyíkéyìí tí wọ́n tíì ṣàwárí nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́ wọ́n ti rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àdàkọ apá díẹ̀ tàbí apá tó pọ̀ nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ ní ayé ìgbàanì. Ọ̀kan lára àjákù àwọn ìwé yìí ni ìwé Ìhìn Rere Jòhánù, tí wọ́n kọ ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn èyí tí àpọ́sítélì Jòhánù fúnra rẹ̀ kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Kí nìdí tó fi gbàfiyèsí pé kò sí èyí tó pa run nínú gbogbo àdàkọ Bíbélì? Báwo sì ni àwọn Bíbélì tó wà lóde òní ṣe pé pérépéré sí tá a bá fi wé èyí tí àwọn òǹkọ̀wé ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ?

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ìwé Míì Tí Wọ́n Kọ Láyé Ìgbàanì?

Tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìwé tí àwọn orílẹ̀-èdè míì tí wọ́n múlé gbe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ, a máa rí i pé bí Bíbélì kò ṣe pa run yani lẹ́nu gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, aládùúgbò ni àwọn ará Fòníṣíà jẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹgbẹ̀rún ọdún àkọ́kọ́ ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Gbogbo àwọn tó wà ní àgbègbè Mẹditaréníà ló mọ bí àwọn oníṣòwò orí omi yìí ṣe máa ń kọ álífábẹ́ẹ̀tì wọn. Wọ́n tún ń jèrè gọbọi látara òwò òrépèté tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú àwọn ará Íjíbítì àti Gíríìsì. Láìka gbogbo èyí sí, ìwé ìròyìn National Geographic sọ nípa àwọn ará Fòníṣíà pé: “Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ sórí òrépèté ló ti bà jẹ́ tán débi pé nípasẹ̀ àwọn ohun tí àwọn ọ̀tá àwọn ará Fòníṣíà sọ lòdì sí wọn nìkan la fi lè gbọ́ nípa wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtàn fi hàn pé àwọn ará Fòníṣíà ní àwọn ìwé ìtàn tó ṣe pàtàkì, gbogbo rẹ̀ ló ti bà jẹ́.”

Àwọn ìwé tí àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì kọ ńkọ́? Bí ẹní mọ owó ni àwọn èèyàn ṣe mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ tàbí tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri tẹ́ńpìlì àti àwọn ibòmíì nínú ìlú náà. Àwọn ará Íjíbítì tún ní òkìkí fún bí wọ́n ṣe máa ń sọ òrépèté di ohun èlò ìkọ̀wé. Àmọ́, Ọ̀gbẹ́ni K. A. Kitchen tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó wà nílùú Íjíbítì sọ nípa àwọn nǹkan tí àwọn ará Íjíbítì kọ sórí òrépèté pé: “Wọ́n ti fojú bù ú pé èyí tó lé ní mẹ́sàn nínú mẹ́wàá gbogbo òrépèté tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sínú rẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún ṣáájú kí Gíríìsì àti Róòmù tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ló ti bà jẹ́ tán pátápátá.”

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ará Róòmù kọ sí orí òrépèté? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Roman Military Records on Papyrus ṣe sọ, ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni wọ́n máa ń san owó fún àwọn ọmọ ogun Róòmù, orí òrépèté ni wọ́n sì máa ń kọ bí wọ́n ṣe san owó náà sí. Wọ́n fojú bù ú pé á ti tó igba àti mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n mílíọ̀nù [225,000,000] àkọsílẹ̀ owó ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti tẹ̀ sórí òrépèté fún ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún, ìyẹn láti ìgbà ìṣàkóso Augustus (ọdún 27 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí 14 Sànmánì Kristẹni) sí ìgbà ìṣàkóso Diocletian (ọdún 284 sí 305 Sànmánì Kristẹni). Mélòó nínú wọn ló ṣẹ́ kù? Méjì péré ni wọ́n rí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣeé kà?

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé díẹ̀ nínú àwọn àkọ́sílẹ̀ ayé ìgbàanì tó wà lórí òrépèté ló ṣì wà títí dòní? Àwọn ohun èlò ìkọ̀wé tó lè bà jẹ́, irú bí òrépèté àti èyí tí wọ́n sábà máa ń lò dáadáa, ìyẹn awọ, máa ń tètè bà jẹ́ ní ìgbà òjò. Ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Torí bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí, àwọn òrépèté tí wọ́n kọ ní [ẹgbẹ̀rún ọdún àkọ́kọ́ ṣáájú Sànmánì Kristẹni] lè má bà jẹ́ tí wọ́n bá tọ́jú rẹ̀ sí aṣálẹ̀ tàbí inú ihò àpáta tàbí ibi tí omi kò ti lè kàn án.”

Àwọn Ìwé Inú Bíbélì Ńkọ́?

Ẹ̀rí fi hàn pé orí àwọn ohun èlò tó lè tètè bà jẹ́ ni wọ́n kọ Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí bí àwọn ará Fòníṣíà, Íjíbítì àti Róòmù náà ṣe kọ àwọn àkọsílẹ̀ wọn sórí rẹ̀. Báwo wá ni àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kò ṣe pa run, tó fi wá di ìwé tí wọ́n tíì tẹ̀ jù lọ ní gbogbo àgbáyé? Ọ̀jọ̀gbọ́n James L. Kugel sọ ìdí kan. Ó ní, wọ́n ṣe àdàkọ Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ “láìmọye ìgbà, kódà ní àkókò tí wọ́n ṣì ń kọ Bíbélì pàápàá.”

Báwo ni àwọn Bíbélì òde òní ṣe bára mu pẹ̀lú àwọn ìwé àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì? Ọ̀jọ̀gbọ́n Julio Trebolle Barrera, tó wà lára àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó ń ṣàyẹ̀wò, tó sì ń tẹ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé àfọwọ́kọ ìgbàanì tí wọ́n ń pè ní Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, sọ pé: “Àdàkọ Bíbélì èdè Hébérù tí wọ́n ṣe péye lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, kò sí ìwé ìtàn tó gbajúmọ̀ ní èdè Gíríìkì tàbí èdè Látìn tó péye bíi ti Bíbélì yìí.” Ọ̀gbẹ́ni F. F. Bruce, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé Bíbélì tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún sọ pé: “Ẹ̀rí tó wà nípa Májẹ̀mú Tuntun ju ti ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tí àwọn gbajúgbajà òǹṣèwé kọ lọ fíìfíì, kò sì sí ẹnikẹ́ni tó ta kò wọ́n.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Tó bá jẹ́ pé àpapọ̀ àwọn ìwé tí àwọn gbajúgbajà òǹṣèwé yìí kọ ni Májẹ̀mú Tuntun ni, kò sẹ́ni tó máa ta kò ó.” Ó dájú pé, ìwé tó gba àfiyèsí ni Bíbélì lóòótọ́. Ṣé o máa ń wá àkókò láti kà á ní ojoojúmọ́?—1 Peter 1:24, 25.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

“Àdàkọ Bíbélì èdè Hébérù tí wọ́n ṣe péye lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, kò sí ìwé ìtàn tó gbajúmọ̀ ní èdè Gíríìkì tàbí èdè Látìn tó péye bíi ti Bíbélì yìí.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Julio Trebolle Barrera

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àwọn ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tàbí Májẹ̀mú Láéláé ló ṣì wà títí dòní àti ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tàbí Májẹ̀mú Tuntun

[Àwọn Credit Line]

Apá òsì: Todd Bolen/Bible Places.com; Apá ọ̀tún: Ibi tí wọ́n ń kó ìwé sí ní Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti àwọn ará Ísírẹ́lì, nílùú Jerúsálẹ́mù

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Látinú Ìwé The Parallel Bible, The Holy Bible, 1885