Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 14

Báwo La Ṣe Lè Mọ Ìjọsìn Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Báwo La Ṣe Lè Mọ Ìjọsìn Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Ohun tá a jíròrò nínú ẹ̀kọ́ 13 fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Àmọ́, a jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wa lọ́nà tó máa mú inú rẹ̀ dùn. “Ìjọsìn [tàbí ẹ̀sìn]” wo ni inú Ọlọ́run dùn sí? (Jémíìsì 1:27, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì kọ́ni.

1. Báwo la ṣe lè mọ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà jọ́sìn òun?

Inú Bíbélì la ti lè mọ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà jọ́sìn òun. Jésù sọ fún Ọlọ́run pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Àwọn ẹ̀sìn kan kì í kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ èèyàn àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n fi ń kọ́ni. Ó sì yẹ ká mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí àwọn tó “kọ àṣẹ Ọlọ́run sílẹ̀.” (Ka Máàkù 7:9.) Àmọ́, tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú ìjọsìn wa, tá a sì ń fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò, inú Ọlọ́run á máa dùn sí wa.

2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa jọ́sìn Jèhófà?

Nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, a ò gbọ́dọ̀ mú nǹkan míì mọ́ ìjọsìn rẹ̀. (Ìfihàn 4:11) Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká máa sin òun nìkan ṣoṣo, ká má ṣe sin òrìṣà èyíkéyìí, ká má sì lo ère nínú ìjọsìn wa.​—Ka Àìsáyà 42:8.

Ìjọsìn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘mímọ́, kó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà’ lójú Jèhófà. (Róòmù 12:1) Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àwọn ìlànà rẹ̀ mu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń nífẹ̀ẹ́ ìlànà rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé e. Wọn kì í ṣe ohun tó máa pa wọ́n lára, irú bíi mímu sìgá, mímu igbó, fífín tábà tàbí aáṣà, lílo oògùn olóró tàbí mímu ọtí lámujù. a

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ń jẹ́ ká lè máa “yin Jèhófà . . . nínú ìjọ.” (Sáàmù 111:1, 2) Ọ̀kan lára ọ̀nà tá à ń gbà yin Jèhófà ni pé a máa ń kọrin ìyìn sí i. (Ka Sáàmù 104:33.) Jèhófà ní ká máa lọ sí ìpàdé torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ̀ pé àwọn ohun tá à ń kọ́ níbẹ̀ máa jẹ́ ká lè gbádùn ayé wa títí láé. Tá a bá ń wá sípàdé, a máa ń fún ara wa níṣìírí, ó sì máa ń ṣe wá láǹfààní.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Wo ìdí tí Jèhófà fi sọ pé ká má ṣe lo ère nínú ìjọsìn wa. Bákan náà, kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà pàtàkì tá a lè máa gbà yin Ọlọ́run.

4. A ò gbọ́dọ̀ lo ère nínú ìjọsìn wa

Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa lo ère nínú ìjọsìn wa? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì nígbà táwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run fi ère jọ́sìn rẹ̀?

Àwọn kan ń lo ère nínú ìjọsìn wọn, torí wọ́n rò pé ó máa jẹ́ káwọn sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́, ṣé ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn ò ní mú kí Ọlọ́run jìnnà sí wọn? Ka Ẹ́kísódù 20:4-6 àti Sáàmù 106:35, 36, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ère tàbí ohun míì wo lo rí táwọn èèyàn ń lò nínú ìjọsìn wọn?

  • Báwo ló ṣe máa ń ri lára Jèhófà táwọn èèyàn bá ń lo ère nínú ìjọsìn wọn?

  • Ṣé o rò pé ó yẹ ká máa lo ère nínú ìjọsìn wa? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

5. Tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo, a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké

Wo fídíò tó kàn kó o lè rí i pé tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tọ́, a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké. Wo FÍDÍÒ yìí.

Ka Sáàmù 91:14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa tá a bá ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé òun nìkan ṣoṣo là ń sìn?

6. Ọlọ́run là ń jọ́sìn ní ìpàdé ìjọ

Bá a ṣe ń kọrin tá a sì ń dáhùn ìbéèrè nípàdé ìjọ, ńṣe là ń yin Jèhófà tá a sì ń fún ara wa ní ìṣírí. Ka Sáàmù 22:22, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé o máa ń gbádùn ìdáhùn tó ò ń gbọ́ láwọn ìpàdé wa?

  • Ṣé ìwọ náà á múra sílẹ̀ kó o lè dáhùn nípàdé?

7. Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá sọ ohun tá a kọ́ fún àwọn èèyàn

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà sọ ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì fáwọn èèyàn. Ka Sáàmù 9:1 àti 34:1, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí lo kọ́ nínú Bíbélì tí wàá fẹ́ sọ fún ẹnì kan?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Bó bá ṣe wu kálukú ló lè sin Ọlọ́run.”

  • Kí lèrò tìẹ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tá a bá ń jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wa nìkan ṣoṣo, tá à ń yìn ín láwọn ìpàdé ìjọ, tá a sì ń sọ ohun tá a kọ fáwọn èèyàn, inú rẹ̀ á máa dùn sí wa.

Kí lo rí kọ́?

  • Báwo la ṣe lè mọ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà jọ́sìn òun?

  • Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa jọ́sìn?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa jọ́sìn pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ka ìtàn yìí kó o lè rí bí obìnrin kan ṣe bọ́ lọ́wọ́ ìbọ̀rìṣà. Àkòrí ìtàn náà ni “Mi Ò Kì Í Ṣe Ẹrú Òrìṣà Mọ́.”

“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, July 1, 2011)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa dáhùn ìbéèrè nípàdé ìjọ.

“Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ” (Ilé Ìṣọ́, January 2019)

Wo fídíò yìí, kó o lè rí bí ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe jàǹfààní nípàdé ìjọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un láti lọ síbẹ̀.

Jèhófà Bìkítà Nípa Mi (3:07)

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ẹ̀sìn Kristẹni ló ni àgbélébùú, àmọ́ ṣó yẹ ká máa lò ó nínú ìjọsìn wa?

“Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn Wọn?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

a A máa jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ yìí nínú àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níwájú.