Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń Kí Ẹ Káàbọ̀ Sílé

Jèhófà Ń Kí Ẹ Káàbọ̀ Sílé

Wà á jáde:

  1. 1. Ṣe ló dà bí pé àná ni

    Nígbà tó o morúkọ mi,

    Tó sì dọ́kàn rẹ.

    O wá ṣáko lọ.

    O fara dà á fúngbà díẹ̀

    Ò ń rántí ohun ayọ̀,

    Ó wà lọ́kàn rẹ láti pa dà wá.

    (ÈGBÈ)

    Káàbọ̀, ọ̀rẹ́ mí.

    Ó ṣì lè ṣàtúnṣe.

    Dúró sọ́dọ̀ mi

    Ọ̀dọ́ mi làlàáfíà

    Ayérayé wà

  2. 2. Mo fẹ́ kó o mo’un tó yẹ kó o ṣe

    Kó o lè pa dà wá sílé

    Kítura ọkàn sì lè jẹ́ tìrẹ.

    Má bẹ̀rù, màá gbà ọ́ pa dà;

    Èmi nibi ààbò rẹ.

    Inu rẹ máa dùn

    Pó o pa dà bẹ̀rẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Káàbọ̀, ọ̀rẹ́ mí.

    Ó ṣì lè ṣàtúnṣe.

    Dúró sọ́dọ̀ mi

    Ọ̀dọ́ mi làlàáfíà

    Ayérayé wà

    Kú àbọ̀.