Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Fẹ́ Fi Ayé Mi Sìn Ọ́

Mo Fẹ́ Fi Ayé Mi Sìn Ọ́

Wà a Jáde:

  1. 1. Ọ̀pọ̀ ìpinnu ni mo lè ṣe;

    Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo lè ṣe láyé.

    Mo mọ̀ pé lọ́jọ́ kan máa pinnu;

    Àbí kí n ṣè ‘pinnu yẹn báyìí?

    Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni àwọn tó

    Sìn ọ́ máa ń rí gbà.

    Kò sẹ́nikẹ́ni tá á bá mi ṣèpinnu;

    Ohun tí mo fẹ́ ṣe ni.

    (ÈGBÈ)

    Mo fẹ́ ṣe ìpinnu tí ó yẹ;

    Mo fẹ́ ṣe ohun tí o fẹ́.

    Ràn mí lọ́wọ́, kí n lè ṣàṣeyọrí;

    Mo fẹ́ fayé mi sìn ọ́.

    Mo fẹ́ fayé mi sìn ọ́.

  2. 2. Mo fẹ́ mọ̀ ọ́, kí n sì d’ọ̀rẹ́ rẹ;

    Mo sì fẹ́ níyè àìnípẹ̀kun.

    Mo mọ̀ pé ìwọ ni Ọlọ́run.

    Ìwọ nìkan ni Ọlọ́run mi.

    Ìgbésí ayé ṣe pàtàkì;

    Mó ti wá pinnu pé.

    Ìwọ ni máa fi ìgbà ọ̀dọ́ mi sìn,

    Ìwọ àti Ọmọ rẹ.

    (ÈGBÈ)

    Mo fẹ́ ṣe ìpinnu tí ó yẹ;

    Mo fẹ́ ṣe ohun tó o fẹ́.

    Ràn mí lọ́wọ́, kí n lè ṣàṣeyọrí;

    Mo fẹ́ fayé mi sìn ọ́.

    Mo fẹ́ fayé mi sìn ọ́.

    Mo fẹ́ fayé mi sìn ọ́.

    Mo fẹ́ fayé mi sìn ọ́.