Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Borí Àdánwò

Mo Borí Àdánwò

Wà á Jáde:

  1. 1. Ojoojúmọ́ làdánwò ń wá,

    Àwọn àdánwò ‘gbàgbọ́—àdánwò ‘gbàgbọ́.

    Bó ṣe máa rí kò yé mi tó.

    Bó ti wù kó lè le tó, mo mohun tí màá ṣe.

    Màá kojú wọn pẹ̀lú ìgboyà,

    Èyí gba pé kí n gbára dì;

    Kí n lè mohun tí màá ṣe

    Tí àdánwò náà bá dé.

    Tí àdánwò bá fẹ́ le jù,

    Màá gbàdúrà sí Ọlọ́run.

    (ÈGBÈ)

    Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n borí—

    Onírúurú àdánwò.

    Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n borí,

    Kí n jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.

  2. 2. Wọ́n tún fẹ́ dán ‘gbàgbọ́ mi wò,

    Wọ́n fẹ́ kí n ṣe bíi tiwọn—wọ́n fẹ́ dán mi wò.

    Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń ṣe

    Ohun t’Ọ́lọ́run kò fẹ́—ohun tí kò fẹ́​—

    Wọ́n á fẹ́ kí n di ọ̀rẹ́ àwọn

    Mi ò ní lè máa bá wọn rìn.

    Èmi kò ní fẹ́ kí wọ́n

    Sọ mí dà bí wọ́n ṣe dà.

    Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí,

    Torí náà, kò yẹ kí n bẹ̀rù.

    (CHORUS)

    Mo borí àdánwò.

    Mo jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.

    Mo borí àdánwò.

    O ti fún mi lókun.