Sáàmù 10:1-18
ל [Lámédì]
10 Jèhófà, kí nìdí tí o fi dúró lókèèrè?
Kí nìdí tí o fi fara pa mọ́ ní àkókò wàhálà?+
2 Ẹni burúkú ń fi ìgbéraga lépa ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́,+Àmọ́ èrò ibi tó gbà máa yí dà lé e lórí.+
3 Ẹni burúkú ń fọ́nnu nítorí ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀,+Ó sì ń súre fún àwọn olójúkòkòrò;*נ [Núnì]
Kì í bọ̀wọ̀ fún Jèhófà.
4 Ìgbéraga kì í jẹ́ kí ẹni burúkú ṣe ìwádìí kankan;Gbogbo èrò rẹ̀ ni pé: “Kò sí Ọlọ́run.”+
5 Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń yọrí sí rere,+Àmọ́ àwọn ìdájọ́ rẹ ga kọjá òye rẹ̀;+Ó ń fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣẹ̀sín.*
6 Ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Mìmì kan ò ní mì mí;*Láti ìran dé ìran
Mi ò ní rí àjálù láé.”+
פ [Péè]
7 Ègún, irọ́ àti ìhàlẹ̀ kún ẹnu rẹ̀;+Ìjàngbọ̀n àti jàǹbá wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.+
8 Ó ń lúgọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibùdó;Ó ń pa àwọn aláìṣẹ̀ láti ibi tó fara pa mọ́ sí.+
ע [Áyìn]
Ojú rẹ̀ ń wá àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí.+
9 Ó ń dúró níbi tó fara pa mọ́ sí bíi kìnnìún nínú ihò rẹ̀.*+
Ó ń dúró láti mú ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
Ó ń mú ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́ nígbà tó bá pa àwọ̀n rẹ̀ dé.+
10 Ẹni tó bá kó sí i lọ́wọ́ yóò di àtẹ̀rẹ́, yóò sì ṣubú lulẹ̀;Àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí yóò kó sínú akóló rẹ̀.*
11 Ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Ọlọ́run ti gbàgbé.+
Ó ti gbé ojú rẹ̀ kúrò.
Kò sì ní fiyè sí i láé.”+
ק [Kófì]
12 Jèhófà dìde.+ Ọlọ́run, gbé ọwọ́ rẹ sókè.+
Má gbàgbé àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+
13 Kí nìdí tí ẹni burúkú kò fi bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run?
Ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “O ò ní pè mí wá jíhìn.”
ר [Réṣì]
14 Àmọ́, o rí ìjàngbọ̀n àti ìdààmú.
Ò ń wò ó, o sì gbé ìgbésẹ̀.+
Ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí yíjú sí;+Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ọmọ aláìníbaba.*+
ש [Ṣínì]
15 Ṣẹ́ apá ẹni burúkú àti ẹni ibi,+Kó lè jẹ́ pé nígbà tí o bá wá ìwà burúkú rẹ̀,O ò ní rí i mọ́.
16 Jèhófà ni Ọba títí láé àti láéláé.+
Àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣègbé kúrò láyé.+
ת [Tọ́ọ̀]
17 Àmọ́ Jèhófà, wàá gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+
Wàá mú ọkàn wọn dúró ṣinṣin,+ wàá sì fiyè sí wọn.+
18 Wàá dá ẹjọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba àti ẹni tí a ni lára,+Kí ẹni kíkú lásánlàsàn* má bàa dẹ́rù bà wọ́n mọ́.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “Olójúkòkòrò ń súre fún ara rẹ̀.”
^ Tàbí “Ó ń wú fùkẹ̀ sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.”
^ Tàbí “Mi ò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”
^ Tàbí “nínú igbó.”
^ Tàbí “àwọn èékánná rẹ̀ tó lágbára.”
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Ní Héb., “tó jẹ́ ará ayé.”