Sáàmù 114:1-8

  • Ísírẹ́lì bọ́ lọ́wọ́ Íjíbítì

    • Òkun sá lọ (5)

    • Àwọn òkè ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún bí àgbò (6)

    • Akọ àpáta di ìsun omi (8)

114  Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì,+Tí ilé Jékọ́bù jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè àjèjì,   Júdà di ibi mímọ́ rẹ̀,Ísírẹ́lì di ibi tó ń ṣàkóso lé lórí.+   Òkun rí i, ó sì sá lọ;+Odò Jọ́dánì yíjú pa dà.+   Àwọn òkè ńlá ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àgbò,+Àwọn òkè kéékèèké ń ta bí ọ̀dọ́ àgùntàn.   Kí ló lé ọ léré, ìwọ òkun?+ Kí ló dé tí o fi yíjú pa dà, ìwọ Jọ́dánì?+   Kí ló dé tí ẹ̀yin òkè ńlá fi ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àgbò,Tí ẹ̀yin òkè kéékèèké sì ń ta bí ọ̀dọ́ àgùntàn?   Máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí Olúwa, ìwọ ayé,Nítorí Ọlọ́run Jékọ́bù,+   Ẹni tó ń sọ àpáta di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Tó ń sọ akọ àpáta di ìsun omi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, koríko etí omi.