Sáàmù 51:1-19
Sí olùdarí. Orin Dáfídì, nígbà tíwòlíì Nátánì wọlé wá bá a lẹ́yìn tí Dáfídì bá Bátí-ṣébà lò pọ̀.+
51 Ọlọ́run, ṣojú rere sí mi, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+
Nu àwọn àṣìṣe mi kúrò nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.+
2 Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi,+Kí o sì wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.+
3 Nítorí mo mọ àwọn àṣìṣe mi dáadáa,Ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi* nígbà gbogbo.+
4 Ìwọ gan-an* ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí,+Mo ti ṣe ohun tó burú ní ojú rẹ.+
Torí náà, olódodo ni ọ́ nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,Ìdájọ́ rẹ sì tọ́.+
5 Wò ó! A bí mi ní ẹlẹ́ṣẹ̀,Inú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi* lóyún mi.+
6 Wò ó! Inú rẹ máa ń dùn sí òtítọ́ tó ti ọ̀kan ẹni wá;+Kọ́ inú mi lọ́hùn-ún* ní ọgbọ́n tòótọ́.
7 Fi hísópù wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi, kí n lè mọ́;+Wẹ̀ mí, kí n lè funfun ju yìnyín lọ.+
8 Jẹ́ kí n gbọ́ ìró ayọ̀ àti ti ìdùnnú,Kí àwọn egungun mi tí ìwọ ti fọ́ lè máa yọ̀.+
9 Gbé ojú rẹ* kúrò lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi,+Kí o sì pa gbogbo ìṣìnà mi rẹ́.*+
10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,+Kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sí inú mi,+ èyí tó fìdí múlẹ̀.
11 Má ṣe gbé mi sọ nù kúrò níwájú rẹ;Má sì gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ kúrò lára mi.
12 Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pa dà fún mi;+Kí o sì jẹ́ kó máa wù mí láti ṣègbọràn sí ọ.*
13 Màá kọ́ àwọn arúfin ní àwọn ọ̀nà rẹ,+Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ.
14 Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run ìgbàlà mi,+Kí ahọ́n mi lè máa fi ìdùnnú kéde òdodo rẹ.+
15 Jèhófà, ṣí ètè mi,Kí ẹnu mi lè máa kéde ìyìn rẹ.+
16 Nítorí kì í ṣe ẹbọ ni ìwọ fẹ́, ká ní bẹ́ẹ̀ ni, mi ò bá ti rú u,+Kì í sì í ṣe odindi ẹbọ sísun ló ń mú inú rẹ dùn.+
17 Àwọn ẹbọ tó ń mú inú Ọlọ́run dùn ni ọkàn tó gbọgbẹ́;Ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.*+
18 Ṣe ohun rere fún Síónì nítorí inú rere rẹ;Mọ ògiri Jerúsálẹ́mù.
19 Nígbà náà, inú rẹ yóò máa dùn sí àwọn ẹbọ òdodo,Àwọn ẹbọ sísun àti àwọn odindi ẹbọ;A ó sì fi àwọn akọ màlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “lọ́kàn mi.”
^ Ní Héb., “Ìwọ nìkan.”
^ Tàbí “Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì ni mí látìgbà tí ìyá mi ti.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “Pa ojú rẹ mọ́.”
^ Tàbí “nu gbogbo ìṣìnà mi kúrò.”
^ Ní Héb., “Kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìmúratán.”
^ Tàbí “fojú pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú rẹ́.”