Sáàmù 44:1-26

  • Àdúrà ìrànlọ́wọ́

    • “Ìwọ lo gbà wá” (7)

    • Bí “àgùntàn tó wà fún pípa” (22)

    • “Dìde nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ wa!” (26)

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Másíkílì.* 44  Ọlọ́run, a ti fi etí wa gbọ́,Àwọn baba ńlá wa ti ròyìn fún wa,+Àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,Ní àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́.   Ọwọ́ rẹ ni o fi lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde,+O sì mú kí àwọn baba ńlá wa máa gbé níbẹ̀.+ O fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, o sì lé wọn jáde.+   Kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,+Kì í sì í ṣe apá wọn ló mú kí wọ́n ṣẹ́gun.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti apá rẹ+ àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ló ṣe é,Nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.+   Ìwọ Ọlọ́run ni Ọba mi;+Pàṣẹ ìṣẹ́gun pípé fún Jékọ́bù.*   Agbára rẹ la ó fi lé àwọn ọ̀tá wa pa dà;+Orúkọ rẹ la ó fi tẹ àwọn tó dìde sí wa rẹ́.+   Torí mi ò gbẹ́kẹ̀ lé ọfà* mi,Idà mi ò sì lè gbà mí là.+   Ìwọ lo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,+Ìwọ lo sì kó ìtìjú bá àwọn tó kórìíra wa.   A ó máa yin Ọlọ́run láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,A ó sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí láé. (Sélà)   Àmọ́ ní báyìí, o ti ta wá nù, o ti kó ìtìjú bá wa,O ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde. 10  Ò ń mú kí a sá pa dà níwájú àwọn ọ̀tá wa;+Àwọn tó kórìíra wa ń kó ohun tí wọ́n fẹ́. 11  O fi wá lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa wá jẹ bí àgùntàn;O ti tú wa ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 12  O ta àwọn èèyàn rẹ lọ́pọ̀;+O ò jẹ èrè kankan lórí wọn.* 13  O sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa,Ẹni ẹ̀sín àti ẹni yẹ̀yẹ́ lójú àwọn tó yí wa ká. 14  O sọ wá di ẹni ẹ̀gàn* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Ẹni tí àwọn èèyàn ń rí, tí wọ́n ń mi orí. 15  Ẹ̀tẹ́ bá mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,Ìtìjú mi sì ti bò mí mọ́lẹ̀, 16  Torí ẹ̀sín tí wọ́n ń fi mí ṣe àti èébú wọn,Nítorí pé ọ̀tá wa ń gbẹ̀san lára wa. 17  Gbogbo èyí ti ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ a kò gbàgbé rẹ,A kò sì da májẹ̀mú rẹ.+ 18  Ọkàn wa kò kúrò lọ́dọ̀ rẹ;Ẹsẹ̀ wa kò yà kúrò ní ọ̀nà rẹ. 19  Àmọ́ o ti tẹ̀ wá rẹ́ níbi tí àwọn ajáko* ń gbé;O ti fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀. 20  Ká ní a ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run waTàbí tí a tẹ́wọ́ àdúrà sí ọlọ́run àjèjì, 21  Ṣé Ọlọ́run kò ní mọ̀ ni? Ó mọ àwọn àṣírí tó wà nínú ọkàn.+ 22  Torí rẹ ni wọ́n ṣe ń pa wá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;Wọ́n ti kà wá sí àgùntàn tó wà fún pípa.+ 23  Dìde. Kí ló dé tí o ṣì fi ń sùn, Jèhófà?+ Jí! Má ṣe ta wá nù títí láé.+ 24  Kí ló dé tí o fi fojú rẹ pa mọ́? Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìyà tó ń jẹ wá àti ìnira tó bá wa? 25  Nítorí wọ́n ti bá wa* kanlẹ̀;Wọ́n sì ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀.+ 26  Dìde nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ wa!+ Gbà wá sílẹ̀* nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Fún Jékọ́bù ní ìgbàlà ńlá.”
Ní Héb., “ọrun.”
Tàbí “látinú iye owó wọn.”
Ní Héb., “àfipòwe.”
Tàbí “akátá.”
Tàbí “ọkàn wa.”
Ní Héb., “Rà wá pa dà.”