Sáàmù 27:1-14

  • Jèhófà ni odi ààbò ayé mi

    • Mọyì tẹ́ńpìlì Ọlọ́run (4)

    • Jèhófà ń tọ́jú ẹni kódà tí àwọn òbí ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ (10)

    • “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà” (14)

Ti Dáfídì. 27  Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi+ àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?+ Jèhófà ni odi ààbò ayé mi.+ Ta ni èmi yóò fòyà?   Nígbà tí àwọn ẹni ibi gbéjà kò mí láti jẹ ẹran ara mi,+Àwọn elénìní mi àti àwọn ọ̀tá mi ló kọsẹ̀ tí wọ́n sì ṣubú.   Bí àwọn ọmọ ogun tilẹ̀ pàgọ́ tì mí,Ọkàn mi kò ní bẹ̀rù.+ Bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,Síbẹ̀, mi ò ní mikàn.   Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà,Òun ni mo sì ń wá, pé: Kí n máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+Kí n máa rí adùn Jèhófà,Kí n sì máa fi ìmọrírì* wo tẹ́ńpìlì* rẹ̀.+   Nítorí yóò fi mí pa mọ́ sí ibi kọ́lọ́fín rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù;+Yóò tọ́jú mi pa mọ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀;+Yóò gbé mi sórí àpáta.+   Báyìí, orí mi yọ sókè ju àwọn ọ̀tá mi tó yí mi ká;Màá fi igbe ayọ̀ rú àwọn ẹbọ ní àgọ́ rẹ̀;Màá fi orin yin* Jèhófà.   Fetí sí mi, Jèhófà, nígbà tí mo bá ké pè ọ́;+Ṣojú rere sí mi, kí o sì dá mi lóhùn.+   Ọkàn mi gbẹnu sọ fún ọ, ó ní: “Wá ọ̀nà láti rí ojú mi.” Jèhófà, èmi yóò wá ọ̀nà láti rí ojú rẹ.+   Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi.+ Má fi ìbínú lé ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi;+Má pa mí tì, má sì fi mí sílẹ̀, Ọlọ́run ìgbàlà mi. 10  Kódà, tí bàbá mi àti ìyá mi bá kọ̀ mí sílẹ̀,+Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.+ 11  Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,+Darí mi ní ọ̀nà ìdúróṣinṣin nítorí àwọn ọ̀tá mi. 12  Má fi mí lé ọwọ́ àwọn elénìní mi,*+Nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,+Wọ́n sì ń halẹ̀ pé àwọn máa ṣe mí léṣe. 13  Ibo ni mi ò bá wà, ká ní mi ò ní ìgbàgbọ́Pé màá rí oore Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè?*+ 14  Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+Ní ìgboyà, kí o sì mọ́kàn le.+ Bẹ́ẹ̀ ni, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àròjinlẹ̀.”
Tàbí “ibi mímọ́.”
Tàbí “kọrin sí.”
Tàbí “Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àwọn elénìní mi ṣẹ lé mi lórí.”
Tàbí kó jẹ́, “Mo gbà gbọ́ dájú pé màá rí oore Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè.”